Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K (31)




Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K (31)
Sii Olootu Yoruba Dun,

Pẹlu iroyin ti ọkọ afsona mi gbọ yii, Olorun nikan lo mọ ohun ti yoo jẹ èrè mi. Patapata ko yọwọkọwọ, lẹyinọrẹyin ko si maa ba tiẹ lọ. Sebi bi ọkọ ba kọ ni ọkọ naa ni eniyan yoo pada fẹ. Sugbon ohun ti o se koko ju si mi ni ayewo ti dokita so wi pe oun yoo se fun mi. Ki ori mi saa ko mi yo ninu ọfin aye ti mo wa.

Igba ti ile mo ti dokita gba ẹjẹ mi. Mo sebi ohun ti won yoo fun mi lesi kiakia ni. Dokita ni mo le pada wa bi ọjọ keji lati wa gbo esi ayewo mi. O si fi damiloju wi pe kosi nnkankan mo ati wi pe mo le ma lo si ile ni alaafia. 

Bee lo gba mi ni imoran ki i n ye maa pe lode mo nitori ẹni abi ire ki i rinde oru. Ati wi pe oru ko mọ eni ọ̀wọ̀. Mo dupe lowo dokita, ore ọkọ mi naa lo san gbogbo owó ti won kọ fun wa pe ka san.

Nigba ti a jade sita ni ile iwosan, mo beere lọwọ ore ọkọ mi pe ki ni sise leyin igba ti eri ti a n wa ti tẹwa lọwọ.


O ni ki n fun ohun laaye naa ki ohun sise lori ero ikahunsile naa ka to mo ohun ti yoo sele. (O fe se eda ohun ti a ka sile naa sori foran C.D)

Mo gba ile lo. Igba mo dele, mi o ba iya mi ati aburo mi. Won ni won ti ji lo sibi akanse adura kan. Enu mi ko tile ran ounje kankan. Mo kan saa tun pada sori ibusun mi ni. 

Ki se wi pe orun lo n ku n kun mi, mo kan ronu naa ni. Bi igba ti mo n wo fiimu ni gbogbo re jo loju mi. Lori ero yii ni mo wa ni ipe oko afeson mi wole.  Gbogbo ohun ti o tile n so lori foonu o tile ni itunmo gidi si mi rara. Ohun ti mo le ranti ko ju wi pe mo ranti wi pe o beere wi pe se alafia ni mo wa. Mo si so fun wi pe mo wa ni alafia.


Ko bere bi gbogbo re se lo, emi naa o si se alaye kankan. Leyin eyi ni mo pe omobinrin ti o fi aso bomi ni asiri ni ile itura. (Mo gba number  re ki n to kuro nile itura lojo naa). Mo pe wi pe mi o ni pe ma ko aso re bo.   

O ni ki n ma se iyonu, oni ohun ko si ni eni ise bayii, wi pe mo le ko wa lojo keji.  Mo du pe lowo re. Ile ti mo wa ni yii  ti iya mi ti de ba mi. Mo ko ejo mo ro fun iya mi. Titi ti ile fi su ni ojo naa, omi ekun ni emi ati iya mi n wa mu bi eni wa gari mu.

Mo gba adura fun gbogbo eyin oluka leta mi wi pe e ko ni rogun ekun, ibanuje ko ni ya ile yin ati ode yin. Amin.

Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment