Smiley face

"Ojo Iwaju Orile-ede yii n sẹjẹ" - Lati owo Kehinde Oladeji


Bi oju ba n sepin, o ye ka yoo ka fi han oju ni. Orile-ede yowu ti o ba tori èní ba ola re je, o daju pe yoo sunkun re boba dola, amo kile to posika nko se ohun rere o ti ni baje jina.

Omo eni lere eni, omo eni lola eni ki gbogbo eniyan o dakun ba wa fonrere e seti ijoba ile wa. Ijoba wa fete sile won n pa lapalapa, won fi riroju sile won mu airoju pon. 

Àti kekere ni won ti ma so fun wa nile eko wa pe awa ewe ile yii ni ola Orile-ede yii, titi ti mo si fi dagba ti mo mo owo otun yato sosi ni mo si n gbo gbolohun naa. Bi iro wa ni won n pa fun wa, bi ooto ni eyin naa le o so nisinyi.

E je ka tibipelebe mu oole oro yii je. Eto eko ile yii ti n polukumusu lo patapata sibe awon adari wa o bikita. Omo ti a pe ni ola wa ti a ko ta o ko, ta ko ta o ró lagbara, bawo ni iru omo bee se fe yàn ko yanju. 

Omo ta ko ta o ko la gbe ile taa ba ko ta.
 
Bi e ba de awon ile eko alakobere àti girama ijoba ni ile yii aanu yo se yin. Se ti ayika ti o doti ti opo awon ile iwe naa ma n wa ni ka so ni tabi ti akunfaya ero. 

le iwe ile wa ni mo ti ri ti awon akekoo n gberawon lese ninu iyara ikawe nigba ti ko saga to to. Omo bi ogorin le wa ni iyara ikawe kotopo ti ko ye ko gba ju eniyan Ogun lo. Oorun buruku ti n jade ninu awon iyara naa kii see ko, e wa ni ki Omo o ma saisan onigbameji. Abajo ti opo majesin fin n kanju rorun alakeji ti eje won si n ke tatan fun esan.

Opo awon akekoo yii ni o ni iwe kika. Kii si se wipe gbogbo won naa ni o wu lati ra amo agbara ni o si lowo opo Obi iru won. O wu aaro ko Jo bata ese ni o si. 

Abi se opo to ni omo merin ni suuku ti koi tii ri owo bo won ni yoo ri owo iwe ra fomo. Opo Obi bee loti fi omo won senu ikose nigba ti ipa ti pin, eyi to ba sagidi àti kawe yori yoo nilati kiri ata, kiri ose, kiri gala àti orisirisi kowo iwe o le yo. 

Opolopo awon Omo bee ni o ti sagbako ijamba oko ti won si ti gborun lo, opo ninu won ni won n fipa balo toju ba ti pofiri ti awon miran si ti di ohun etutu fun awon gbomogbomo. E si ni ojoowaju wa o ma seje?

Ninu ofii ninu oola, ti omo ba rójú kawe girama tan ti wo fasiti ijoba, ijangbon miran ni o tun torunbo yen. Aye atijo ni eko ofe ti wa, lonii owo lowo eyin nle ni. 

Yato si owo gegele ti Obi n san ki Omo o to wo fasiti ijoba, leyii ti o ti so opo Obi di onigbese àti alasokan, bi won o ba mooyan oseese ki àti ri àdìmísàn o di ala adiye lasan. Abetele ni o je ki awon miran ti o loye lori o ri fasiti wo ti won si ti gba kamu. Eyi ti o ba lagidi ninu won, pelu opolopo adura, a se idanwo JAMB bi enimaaku ki won to mu. 

E si ni ojo ola Naijiria o ma seje?

Omo to ba wo ile-eko giga ijoba nileyii ko ti ya mura àti lo odun mefa si meje fun eko odun merin ti o fe ko. Eyi ti o ba si ye ko lo odun marunun tabi mefa ki o ya tete fokan si odun meji miran le sori re. Èní ASUU dasele, ola awon lekisora yanselodi ni kii je ki ankawe nile yii o ya boro. 

Osu keta ree ti fasiti Adekunle Ajasin, ni ipinle Ondo, ti wa ni titi pa, ti awon akekoo fasiti Ladoke Akintola (LAUTECH) naa o si mogba ti won yoo pada si sukuu, leyin ti won ti wa nile fun opolopo osu bayii. Opo fasiti si ni o n foju wina sunkere-gbakere to n daamu eto eko ile yii ti kaluku kan n mu mora.

Bi Omo ba tun kawe tan atirise a dogun, atirise a di wahala. Opo odo langba lo n fese gbale titi kiri. Airikansekan lo so imi dole to n fole kiri, a si fowoleran a n wo.  

Ojojumo ni won n tan wa pe odo ni ojo ola Naijiria sibe awon arugbo lo n sejoba. Awon ni won wa ni awon ipo nla-nla ti awon odo langba si n se omo leyin tabi ki won fi won se tóògì ti o ba di asiko idibo. E si je ka ronu, ka panupo ka bole wi, ka ke si ijoba wa leti pe ojoola ile yii n seje. Ki a se nnkan ki nnkan o to se wa!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment