Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K (37)

#ayeOlabisiK37


Bi orisiirisii ero se n wa si mi lokan re e. Mi o le so iye ago to lu tori wi pe ko si ina ti mo le fi ri ago ẹgbẹ ogiri. Amọ mo mọ wi pe ọjọ ti lọ gan-an, a si ti n sun mo aajin.


Gbogbo ẹ ti pa lọlọ bi iboji oku. E mi gan-an o tile mọ igba ti orun gbe mi lo.

Sugbon mo sakiyesi wi pe afẹfẹ tutu kan rara n yo wole lati oju ferese eyi to si n mu oju mi toogbe.


Igba to ya ni mo ri awon okunrin mẹta dudu leti bẹẹdi mi. Awon wo leyi? Mi o ri ran ri oju won, sugbon mo mọ wi pe okunrin ni won.

Won ko wo ẹwu, sokoto penpe lowa nidi won. 

Bee lara won dan bọrọbọrọ bi eni o fi ororo para. Won n wo mi lori ibusun nibi ti mo sun si.

Ẹru ti ba mi, mo lẹ mọle nibi ti mo wa. Ibo ni awon eniyan buruku yii le gba wọle? Se won fọ ilekun ni tabi won ni kọkọrọ ti won lo wọle?

Kaayefi ati jinijini gbon mi, igba to ya ni mo pinnu ki n pariwo boya ti iya mi baji ati awon ara ile won le wa ran mi lọwọ. Bi mo se ni ki n gbiyanju ati pariwo bayii ni won fọwọ bomi lẹnu, won si di mi korobata bi ẹni di igi.


Igba ti won di mi tan tenutenu, awon meeji gbe mi nile nigba ti ẹkẹta won tele won. Won gbe mi jade ninu ile mi o si mo ibi ti won gbe mi lo.


Won fi aso de mi lenu de bi wi pe bi mo se n gbiyan ati pariwo pabo lo jasi. Bẹẹ ni won gbe mi lo ti mi o si le sọ pato ibi ti won gbe mi lọ.

O n semi bi ka tile pade ẹnikan lọna, sungbon eesin lasan ko si loju ọna ti won gbe mi gba.

Won kan saa n gbe mi lo ninu oru dudu yii naa ni. Se ki i se wi pe opin ti de ba igbe aye mi bayii?

Kini awon wonyii fe fi mi se gan-an? Ko ma jẹ wi pe agbanipa niwon won jẹ?

Ẹkun gbigbona gbọn mi lati inu wa. Eegun atiro wọle, eniyan atiro jade. Se kii n se oga mi lo tun ran awon eniyan buruku yii wa?


Eyin ololufe mi, mo fe duro nibi. Ma tun maa tesiwaju to baya.


Adura kan lokan lo wu mi ki n se, wahala to kere ati eyi o tobi ko ni kan yin ni agbara Olorun. Amin

O digba.

Emi ni tiyin ni tooto,
Olabisi K
O si n tẹsiwaju...


















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment