Smiley face

Ariwo @FunkeAkindele ni won pa niluu Biritiko latari #JenifaInLondon

Lati London wo Manchester niluu Oba Elisabeeti, lati bi ojo kerin to fi wo ojo kefa osu kokanla odun 2016, ariwo oserebinrin ile adulawo to rinle ju lo ni Olufunke Ayotunde omo Akindele aya AbdulRasheed Bello.

Bi eniyan ba n wa owo lo to ba pade iyi lona ko dupe lowo ori, nitori gbogbo eni pate oja ko loja re ta warawara.

Jenifa In London, sinima tuntun Funke Akindele, ti won se ayeye afihan re ni United Kingdom ti wa sopin sugbon aseyori ati okiki fiimu naa si wa loke bi osupa.

Opolopo awon oniroyin amuludun ile Afirika ni won si ti bere si ni see lalaye wi pe, oseese ki fiimu alawada naa gba ami-eye nla to ba jade.

Se e ko gbagbe wi pe Jenifa lo gba ami-eye Best Actress In Comedy Role ti 2016 Africa Magic Viewers Choice Awards eleyii to gba latari akitiyan re lori Jenifa Diary.

Olayemi Oniroyin ni oruko mi. Emi gbagbo wi pe, igba die lo ku fun ogo Nigeria lati gbera.

Ko ni pe mo, nigba ti awon eniyan agbaye yoo maa so wi pe Naija laye wa.

Ki Oluwa ko bukun ilu mi ati awon eniyan re. Amin

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment