Smiley face

Seun Egbegbe ti lo foju bale ejo: Won ti silekun kirikiri sile fun un

Seun Egbegbe gege bi afurasi-odaran ti won lo lo jale ninu oja Computer Village n'Ikeji lojo kejilelogun osu kokanlan odun yii ni won ti gbe lo si ile ejo lana Ojobo pelu esun ole jije.

Leyin ti onidajo Aje Afunwa ka esun Egbegbe si i lete gege bi eni to n gbiyanju lati ji awon foonu ti iye owo re to milionu meji ati egberun lona irinwo naira(2.4M), Egbegbe ni oun ko jebi esun naa rara.
Awon eniyan Seun Egbegbe ni kootu lana
Nibayii, ile ejo ti sun igbejo naa di osu keji odun ti n bo. Bakan naa ni onidajo paa lase wi pe, ki won lo fi ololufe Toyin Aimakhu nigba kan ri pamo si kirikiri titi ti won yoo fi ri milionu kan naira ati oniduro meji to rese wa lati daa sile saaju ki igbejo re to pada dide.

Eyi tunmo si wi pe, ti won ko ba ri milionu kan naira san, kirikiri ni Egbegbe yoo ti maa se faaji titi di osu keji odun ti n bo.

Opolopo awon omo eruku ni won ya si kootu majisireeti to wa ni Ikeja lana ti won si n faraki wi pe, awon ma je oju iyalaya oniroyin to ba ya foto Seun Egbegbe. Enikeni ko le sunmo Seun Egbegbe titi to fi ko sinu moto dudu awon elewon ti won fi gbe e lo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment