Smiley face

Idi ti ireti fi wa ninu Odunlade Adekola ati Femi Adebayo nipa ise tiata Nigeria


 
Oni (December 31) ni ojo ibi Femi Adebayo ati Odunlade Adekola, awon agbaoje onise tiata ti ko se fowo ro seyin nigba kankan.


Amoiye ijora ni Femi ati Odun ni ti a n ba so nipa agbara ebun ati agbekale ise opolo to yanranti. Ko fe e si ipa ere ti Femi le ko ti Odun ko le se. Awon mejeeji jo dasaka ninu oro siso, bakan naa ni won si rewa loju eleyii to se pataki ti a ba n so nipa ise amuludun ode iwoyi.

Sugbon sa, Femi Adebayo ti n rese wale lagbo oselu, okan pakaki lo je lara awon oludamoran fun gomina Ipinle Kwara. Awon onwoye nipa oselu si ti bere si salaye wi pe, oseese ki Femi Adebayo omo oga Bello di gomina ipinle re lojo iwaju.

Nipa ti Ogbeni Dagboru, bi o tile je wi pe ipa re lagbo oselu ko ti foju han, sugbon, gege bi akojopo Olayemi Oniroyin, awon kan ni bi bobo naa se pada sileewe le je lati raye joko ninu oselu ojo iwaju.

Eyiowukawi, ti Oluwa oba lase, kadara eda ko si ni tase laelae. Pelu iru opolo ati ebun ti awon ogbontarigi osere yii ni, ipa won yoo laamilaaka lagbo ise tiata ti won ba le ri akaba oselu gun doke.

Gege bi apere, e je ka gba wi pe awon mejeeji di senato tabi  gomina ipinle won, yoo rorun lati lo agbara won fun idagbasoke ise fiimu ile Naijiria eleyii ti ijoba ko kobiara si titi di akoko yii.

Ni ilu Naijiria, okanjua ni opolopo wa – ijoba ati ara ilu, owo ojiji si ni gbogbo wa n wa. Idi pataki re e ti awon olori fi ranri mo epo robi nigba ti MMM lo anfaani okanjua wa lati ja opolopo lole.

Aimoye owo ni ijoba ilu India n pa wole nidi ise fiimu. Teru-tomo si n gbe ni alaafia ati irorun bi won ko tile lepo robi.

Aimoye awon olopolo eda lo wa ni Naija bi Femi ati Odun, eleyii ti ise opolo won le sise fun idagbasoke ilu wa. Sugbon ijoba ni lati se irawon gidi, agbateru, agbekale ilana ati ofin eleyii ti yoo mu ise fiimu tesiwaju.

Pelu ipo ti ise fiimu de ni Naijiria, ko ti buru ju ti a ba ni ileewe ifafiti nla ti yoo je lati ko ise fiimi lojulowo, idasile ibudo nla nibi ti awon elo fiimu ti le di yiya pelu irorun, eto eyawo ni banki fun awon onise fiimu lona to rorun ati ofin to fidi mule eleyii ti yoo daabo bo awon ise opolo won ti ko fi ni ma bo si owo awon alegbeda.

Boya  ki n fi orinkinniwin alaye mi yii sile dojo iwaju. Ajoyo ojo-ibi Femi ati odun la n se lonii. 

Idunnu wa lo si je lati ba won yo. Adura mi ni wi pe irawo won ko ni womi, ola won ko si ni lo seyin laelae. Mo gbadura alaafia, emi gigun ati oore-ofe tuntun lati odo Olorun. Igba odun, odun kan ni. 

#Happy Birthday.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment