Smiley face

Ogo ilẹ Yoruba: Hon Akeem Adeyemi omo Alaafin Oyo pe ẹni ogoji odun (40yrs)

Hon Akeem Adeniyi Adeyemi (Skimeh)

Ka bini nile ọla ko ni ka rinrin iyi lawujọ. Aimọye ori-ade ni won ti sọmọluabi nu dẹni yẹyẹ lawujo nitori ijẹkujẹ. 

Sugbon sa, ti Sango ba n pa araba ti n fa igi iroko ya, bi tigi nla kọ.

Ọmọọba Alaafin Oyo, Akeem Adeyemi ti jẹwo ara rẹ lagbo oselu gẹgẹ bi ojulowo ọmọluabi ti ko gbagbe ile ọla to ti jade wa.

O ti se alaga ibilẹ ri, ko jeun japo saya. Okiki otito inu ati ifẹ ọmọniyan ti fi n sisẹ lọwọlọwọ nile igbimọ asoju-sofin Abuja ti di mimọ fun gbogbo aye.

Nitooto, a-ji-sebi-Oyo-laari, Oyo tia ko ni sebi ẹnibọọdi laelae.

Skimeh, Femi Gbajabiamila ati Alaafin Oyo
Akeem Adeniyi Adeyemi jẹ onirẹlẹ eniyan, kosi ibeere ti won le bi nipa isẹ ilu to gbe dani ti ki i dahun. Gbogbo igba lo si ma n jabọ ibi to ba isẹ de fun awon ara ilu ti won ran nise.

Ki n ma paro tan yin, oko Temitope jomiloju gidi.


Skimeh ati iyawo re, Yeye Temitope Famadewa Adeyemi

Hon Akeem Adeyemi ti gbogbo eniyan tun mo si Skimeh pe eni ogoji odun (40yrs) lonii (8-12-16).

Adura mi ni wi pe Edumare yoo tun bo fun ni ọgbọn, imọ, ẹmi ifinsin, ibẹru Oluwa lati le tesiwaju ninu gbigbi ọgọ Naijiria ga gẹgẹ bi asoju rere ile Yoruba.
#HAppyBirthdaySkimeh #Akinkanju #EniyanPataki Gominalọla
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment