Smiley face

Bayii ni @AdekunleGold se mu wa ranti orirun asọ adirẹ

Adekunle Gold
Awon Yoruba bọ, won ni okùn ko le gun titi ko ma nibi to ti sẹ wa. Bi asọ adirẹ tilẹ di gbajugbaja lonii eleyii ti a le ba pada nibikibi lode agbaye, sugbon iwadii fi ye wa wi pe nnkan bi 1850 ni adirẹ wa saye ni agbegbe ilu Abeokuta eleyii ti n se orirun asọ Adirẹ.

Kini a n pe ni ADIRẸ: Asọ adirẹ ni asọ ti a di lokun ki a to rẹ ẹ sinu aró. Asọ ti a dirẹ sinu omi aró ni won pe ni adirẹ.
Ni igba ìwásẹ̀, gẹgẹ bi itọpinpin Olayemi Oniroyin, oni idile kan pato ti won rẹ asọ adirẹ. Eleyii tunmọ si wi pe, ki i se isẹ ti ẹnikẹni le gbe kalẹ yato si awon to wa lati idile naa.

Agboole Jojola to wa ni Kemta niluu Abeokuta ni won ti kọkọ rẹsọ láró. Arabirin Miniya Jojolola Soetan, eni to jẹ Iyalode eleekeji ti yoo jẹ niluu Ẹgba, lo kọkọ ti asọ bọnu omi aro. Gbogbo awon omobirin ti won bi ninu idile yii ati awon iyawo won ni won si n kọ bi won se n rẹsọ adirẹ
Bi o tilẹ je wi pe isẹ obirin ni adirẹ sise lati ibẹrẹ pẹpẹ, sugbon nigba ti yoo fi di ọdun 1930, ati ri awon okunrin nidi ise naa. Lati nnkan bi odun 1960 ni iyi nla si ti deba adire nipa awon kemika ati omi aro orisiirisii ti awon èèbó ko wa lati oke okun eleyii to mu gbayii sii kaakiri agbaye.
Laye ode oni, bi o tilẹ je wi pe Abeokuta ni orirun asọ adire, adirẹ ti di ohun ti won rẹ tabi se kaakiri agbaye ti ko si pon dandan fun won lati wa lati idile to se idasile rẹ.
Omo bibi ilu Eko ni Adekunle Kosoko ti gbogbo eniyan mo si Adekunle Gold. Idile oba Kosoko Eko lo ti wa, o si ni ibatan pelu gbajugbaja osere tiata, Jide Kosoko. 

Bi o tile je wi pe ati nnkan bi omo odun meedogun lo ti bere si korin sugbon ise ona ayaworan lo kawe gboye le lori nile ẹko giga.

Opolopo igba ni Adekunle Gold fi n se igbelaruge fun asọ ibile wa, aso adire, eleyii ti ko wọpọ laaarin awon akegbe rẹ.
Lati mo si nipa agbaojẹ onkorin naa, ati nipa awon ise orin rẹ, ma royin ki ẹ yẹ itakun-agbaye re wo nibi : http://www.adekunlegold.com/
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment