Smiley face

Iru idajọ wo ni ile-ẹjọ fẹ da fun Seun Egbegbe losu keji odun 2017?

Seun Egbegbe lagbo ariya
Seun Egbegbe to rin irin ajo lọ siluu Malaysia lẹyin ti won da a silẹ lẹyin ẹsun ole jija ni won ti kefin rẹ nigboro aye bayii.

Ode ariya ni won ti gburo Seun Egbegbe lọsẹ to koja eleyii to fi han gbangba wi pe, o ti pada de lati ilu Malaysia.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Seun Egbegbe gbera lo si ilu Malaysia leyin ti ile ejo sun igbẹjọ rẹ di jọ kẹjọ osu kejiodun 2017 ta a wa yii.

Aimoye awon eniyan ni won si n ro wi pe maanu naa fi ọgbọn salọ ni, ati wi pe, o seese ko farasoko siluu Malaysia raurau.
 
Lara awon eniyan ti won tako bi won se gba ki ọkunrin naa ri irin-ajo jade ni Naija ni Kemi Omololu-Olunloyo. Ninu ọrọ Kemi Olunloyo lo ti naka abuku si awon olopaa Naijiria gẹgẹ bi awon agbofinro ti ko mọse won nise.
 
Ninu akojopo iroyin OlayemiOniroyin Agbaye nipa ohun ti awon eniyan n so kaakiri ayelujara, awon kan so wi pe, isẹlẹ naa seese ko jẹ isẹ aye tabi ki gbajumo naa fi soogun okiki. 

Awon kan si tun so wi pe misiteeki lasan lo sẹlẹ lọjọ naa, alaye won naa ni wi pe, gbajumo naa koja ẹni to le lọ soja lati lọ ji foonu. Ohun ti won gbiyanju lati sọ naa ni wi pe,  Seun Egbegbe ki i se eniyan yẹpẹrẹ

Sugbon Sa, ọjọ kẹjọ osu keji (8-2-2017) ti fẹ ẹ wole de. Ti ọjọ naa ba de, iru idajọ wo ni won fẹ da fun ololufee Toyin Abraham (Eni ti n jẹ Toyin Aimakhu tẹlẹ) nigba kan ri?

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment