Smiley face

Itan Isedale Yoruba: Lamurudu ko dele Ife -Adeleke Ademola

E ku igbinyanju, b'omode o ba'tan, to ba ti ba aroba, AROBA gan-an Baba Itan ni.

Gegebi ise iwadi itan isedale Yoruba, won a maa ki Oduduwa bayi "agegere ogan, t'aa lo mo iyaa re, t'aa lo mo baba to bi o lomo, dida lo dawa lat'oke wa (Afewonro) too fi n je Odu to da iwa."

Lamurudu ti won fi ye wa wi pe oun ni Baba Oduduwa ko bawon de'le-lfe, fun idi eyi, kosi aridaju wi pe Oduduwa mu Baba to bii lomo wa si lle-lfe .

Itan to gbe itan pon lo fi ye wa wi pe Lamurudu kan wa nibikan tii se Baba Oduduwa.

Koda nigba ti won fewon ro s'ori lle lfe won ba awon eda kan nibe, gegebi a ti rii gbo, fun idi eyi iwa ikonimora ti a mo Yoruba mo, lo jeki itan wa gbe araa won pon titi d'ojo oni.

K'a too le tu itan kan Baba Lamurudu, ona yoo ji bi ile Awurebe.

ODUDUWA lo mu olaju wo ile Kaaro oo jiire bi.

Gegebi itan se so, ewe ati mariwo ni won n san bii bante laye igba naa, Baba wa yi lo kowa nipa ise aso hi hun ati bi a tii wo'so, o si tun da oro Oba jije sile ati awon asiri to ro mo ipo Oba jije pelu bi asiri agbara omo adulawo se wulo fun ilera eda.

Oduduwa lo gbe eto Oselu awon L'Oba L'Oba wo ile Kaaro oo jiire bi.

Idi niyi ti a fi gba pe, Oduduwa ni Baba Awa Yoruba.

Yoruba Dun o."

Alaye oke yii lo je idahun Dokita Ademola Adeleke si ibeere isale yii, eleyii to jewo lori ate Yoruba Dun.

Tani baba Yoruba? A(Oranmiyan) b(Odudua) c(Lamurudu)?

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments: