Smiley face

Awon dokita ti won jo konkonbilo ni yara ise abe ti padanu ise won

Ni ilu Colombia, awon dokita bi marun-un pelu noosi ni won ti da duro bayii nigba ti fidio kan lu jade nibi won ti n jo yika alaisan saaju ki won to sise abe fun un.

Alaisan to wa lese kan aye, ese kan orun yii ni o wa ni ihoho nigba ti awon dokita ti won fe sise abe fun un bere si ni seyeye alaisan naa, won korin bakan naa ni won jo konkonbilo yika alaisan naa.

Sugbon sa, awon alase ile iwosan ti toro aforiji lowo awon ara ilu nigba ti won so wi pe, gbogbo awon ti won foju han, ati eni to gbe foonu dani ti n ya "fiimu agbelewo" ni awon ti daduro lenu ise. Won ni iru iwa bayii tapa si ofin ati agbekale ise iwosan.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment