Smiley face

Itandowe ni owe; "OWO OMODE Ò TÓ PEPE

N JE E MÒ?
 Image result for african children playing
Ododo ni wi pe itandowe ni owe; "OWO OMODE Ò TÓ PEPE TÀGBÀLAGBÀ Ò WO AKÈRÈGBÈ" Àmo inú ese ifa gan an ni itan náà ti sè. Ki alaye mi o baa le yee yin, e je ki a bere pelu odu 

Iwori Meji ti o wi pe;
Owo ewe o to pepe;
Ti agbalagba ò wo akèrègbè
Isé ewe be agba
Ki o mase kò mó;

Gbogbo wa ni a nise a jo n be ra wa....... (Wande Abimbola 1977:16) 

Bi a bá wá fé tókasi itan ti o je igi eso owe yìí , báyìí ni itan náà se lo;

Alájàpá ni Iya Akanni, Atoja kan de omiran si ni o máa n ra oja. Bi o ba ná oja Ajébamidele lonii, yóò ná Mámu lola, yoo na Aráròmi lótunla abbl.

Ni Ojo kan, Iya Akanni kiyesi pe eran kan n ni oode won lara latari wi pe bi o se n le eran náà, ni eran yìí tun n pada. Ni Iya Akanni ba yaa dogbon si i, ko gbe ounje akanni si inu agbon ti o máa n gbé e si tele Nítorí iberu ki eran o ma baa je ounje Omo re, ni o ba nawó gbe ounje sori pepe kenu eran o ma baà to, ó si ba orò ajé tirè lo.


Elegbe pé ebi ló lé Akanni wolé láti ilé-èkó rè ni, agbara káká ni ó fi bó aso silè ki o to máa wá ounje osan re kiri inu ile nigba ti ko ri I nínú agbòn ti Iya re máa n ba a gbé ounje si. Ibi ti o ti sunupò, ni o ti tajú kán ri abo ounje re lori pepe òòdè won, ó wá Ku bi yoo se gbé e. Ori ironu bi yóò ti ri i gbé ló wà, ti o fi bo si òde, O ri baba agba ti o n fi ako okuta pón àdá. 


O nà félé ki baba, o wa be baba lati dakun ba oun nawo gbe ounje oun lori pepe. Baba ni "iwa oyaju ló wu, omode kii be agba nise" Akanni toro aforijin, o si gbe apoti tisè lati gbe ounje re.

Kò pé pupo ti o jeun tan, ni baba ba pe e, pe ki o dakun ba oun yo eso oóyó nínú akeregbe nitori pe enu re kere fun owó òun. Akanni ni ki baba o má binu wi pe oun kò nii leè baa kowo bo akeregbe. Baba ba dide, o ja oré lati na Akanni fun pe o ko isé ti oun bè é. Akanni sa bo si arin aba ki egba baba o ma baa bà á.


Bàbá Àkànjî ti o ri won ni o wa da si òrò náà wi pe; "Bi e ba na omode yìí , e kan fagba re e je lasan ni, Nítorí pe gbogbo wa la jo n wulo fun ara wa. 


Omo be yin nise, e kò, e wa ni komo o fi tipatikuuku se isé fun yin, ko seese Nítorí onikaluku lo ni iwulo tirè, bowo Akanni o se to pepe náà ni tiyin náà o wonu akeregbe."Baba agba gba asise re, won si fe ki elomiiran o kógbón nínú isele náà ni won fi so o di owe wi pe; OWÓ OMODE Ò TÓ PEPE, TÀGBÀLAGBÀ Ò WO AKÈRÈGBÈ.
ÈKÓ TI ÀWON ÀGBÀ FÉ KI Á KÓ:

* Iran ara eni lówó: Kágbà o ran omodé lowo, komode náà o sise fágbà.


 Orisun: Olùkó Èdè Yorùbá Arb
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment