Smiley face

Kini mo le je gbegbe ore mi, John Oluwapo Emmanuel?

Oluwapo ati Oluwaseun
Boya ki n pe eleyii ni Leta Mi Si John Emmanuel ati aya re, Seun. Aimoye anfaani ni John ti semi to je wi pe mi o le san tan. Aimoye ife lo ti fi han mi eleyii to n je ki n ma wo gege bi angeli Oluwa. Gbogbo igba ti mo ba fe iranlowo ni Johannu ma n dide lati se gbogbo ohun ti ipa re le se fun mi, lati ileewe titi di akoko yii.

Lojo ti mo se igbeyawo, lati ibere titi dopin, iwaju ni John durosi. Bo se n nawo ni i nara. Awon kan tile sebi oun loko iyawo ni.

Kini ka ti wa gbo wi pe John segbeyawo mi o raye lo. 

Ore mi dariji mi. 

O wu inaki ko gbe lawujo eniyan, iru idi re ni ko je. ka jeran titi lenu a ma dun yungbayungba, onfa ona ofun ni ko je ka gbadun eran namo gidi. Ko ba wu mi ki jalaga lojo tore mi n segbeyawo tuntun, ohun mo gbe dani ni mi o ribi gbeka o.

John dariji mi, lai pe mo bo wa ba o ko mo.
John dariji mi, ojo to ba sile tuntun dandan ni ki n debe sariya.
Ore mi ma binu, ojo to ba joye maa kewi nibe dandan ni
Ayanfe mi, laipe, mo si bo wa tuuba nile re.
Titi di akoko naa, ma gbe ni alaafia pelu aya re, ninu owo, omo, ayo, aiku, igbega ati oore ofe latoke. 

Emi ni ore re tooto,
Olayemi Olatilewa


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment