Smiley face

Seun Egbegbe bu sekun leyin osu meji logba ewon

Leyin bi osu meji ti Seun Egbegbe ti wa ni ahamo awon olopaa, omokunrin naa ti bu sekun bayii latari airi eni ti yoo duro fun un.

Ninu ejo ti adajo daa ninu osu keji odun yii ni won ti ni ki won daa okurin naa sile ti o ba ti ri oniduro meji pelu milionu marun-un nigba ti ejo re yoo ma tesiwaju?

Oniduro naa gbo je osise ijoba onipele merindinlogun, oniduro naa gbodo ni iwe ile re ti yoo fi sile pelu awon iwe irina si oke okun.

Sugbon gbogbo ilakaka Seun Egbegbe lati ri oniduro ti yoo ko gbogbo ohun ti ile ejo n beere fun yii lo ja si pabo.

Ti e ko ba gbagbe, leyin asemase foonu ti Seun Egbegbe lo jigbe ni agbegbe Ikeja, omokunrin naa tu lo lu awon gambari ti won sewo ni jibiti owo dollar.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment