Smiley face

Aye n sedaro leyin odun kan ti Mama Remdel ti lo simi

Kato ri agbe o dile aro. Ka to ri aluko o dikosun. Eniyan ti yoo foju kan lekeleke alaso funfun o dile ikefun. Ka to foju kan Abiodun Ibitola, o tun di ojo ajinde.

Kosi eni to waye ti ko ni lo sorun, ohun ti kaluku ba se sile naa laye a ma royin nigba to ba lo tan.

Arabirin Abiodun Ibitola titi gbogbo eniyan tun mo si Mama Remdel lo ti pe odun kan bayii to ti lo ba Olugbala re loke orun.

Arabirin Abiodun gbe igbe aye iwa mimo, aimoye awon eniyan to fasoke ni won ko le gbagbe ore to se fun won laelae.

Lonii, ebi, omo, ore, ojulumo, alabasise ati gbogbo omo Naijiria ni won sedaro leyin akoni obirin bi okunrin.

Ki Oba oke tun bo ba wa duroti gbogbo ebi oloogbe patapata. Amin

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment