Smiley face

Oriki Ile-Ife

Omo onife abure omo adade oworemo, Ife omo olodo kan otere
Omo olodo kan otara, omo olodo to n san wereke to n san wereke tode eyinkule osile todabata, iran asakeke o gbudo bumu bee niran ababaja o gbudo buwese, oni soboro ni yoo mumi odo naa gbe.

Won ki i duro ki wa nIfe Ooni,
won kii bere ki wa nife Ooye
Ko ga-ko bere laa ki wa nIfe Oodaye

Bi won ko si ki wa nIfe, won ki i to abere
Oju bintin la fi n wo ni
Emi wa ki oba nIfe, mo lo akun
Oba nii lo sese efun
Adimula, won a ni apalado
Bante gbooro, ni mufe wumi
Segi owo ati tese,
Kafari apakan ka dapakan si
Yeepa orisa, aso funfun
Oun nii mu ile Olufe wumi
Apadari eni, apalado eniyan
Ebo ojoojumo, nii mu ile won su nii lo

Awa lomo oni fitila rebete
Ina ko nii ku nibe tosan toru
Ibe ni baba wa gbe n ka owo eyo

Awa lomo onilu kan, ilu kan
Ti won n fawo ekun se
Aketepe eti erin ni won fi nse osan re
Onikeke ko gbodo jo
Ababaja ko gbodo yese
Kikida onisoboro ni yoo jo ilu naa ya

Ogun ko see da gbe
Baba taani ko mo wi pe irin ti po lagbede

Oun ti o ba mu alagbede, ko ni mu eni to n fin ina

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment