Smiley face

Omo Naijiria ko leta leyin iku Pastor Ajidara

Okan ninu awon ololufe fiimu agbelewo ile Naijiria, Arabirin Onibonokuta Adeola Afolabi ti ko leta leyin iku okan lara awon osere tiata, Samuel Adesanya, eni ti gbogbo eniyan mo si Pastor Ajidara.

Osere yii lo jade laye lojo keje osu karun un odun 2017 leni odun mejilelogota(62) latari aisan kidirin.

Iku osere naa banilokanje, eleyii lo si sokunfa leta ti Arabirin Afolabi ko sita. Leta naa ni yii nisale.

************

Inu mi yio dun gidi gan ti e ba le ba mi gbe erongba mi yii jade sita. Ki awon omo Yoruba atata naa le da si. Tori ogbon omode ki je ki a pe agba ni were tabi ki e fi sowo si egbe awon osere lapapo.

Kilode ti o fi je pe igba ti aisan ba ti won wo lara tan ni won maa sare fun iranlowo owo. Ti ijoba ko ba le ran wo lowo. Kilode ti awon funrara won kole ran ara won lowo.

Orisirisi ona ni won si le gba se eleyi ti yio si mu ki won le tete ran won lowo lati deku iku aitojo ti pa awon ololufe wa ninu egbe yii

1. Won le penu po ki won ni ki omo egbe kookan maa da owo sinu egbe lododun. Iru owo bayi yio wa fun iranlowo pajawiri tabi isele airotele fun awon omo egbe

2 Wo le maa seto ikowojo lododun tabi odun mejimeji si ra won.

3. Tabi ki won se ere agbelewo kan ni oruko egbe, ere (profit) ti won ba ri ni Ori ere (film) naa yio lo si apo egbe.

4. Awon owo ti won ba ko Jo, won le fi sowo ti yio tun maa mu owo wole fun won, bi gbongan ti won ti le se ayeye, ile igbafe, ile iworan ati orisi ohun miran to tun le mu owo wole, gbogbo owo ti won ba ri yio lo si apo egbe.

5. Wo le gbe oruko egbe si ori ero ayelujara pelu nomba ile ifowopamo won ati alaye oun ti won fi se be. Opo awon ololufe won ni Nigeria ati oke okun yio ni anfani lati ran won lowo.

Ko da awon ijoba ti ko fe da si won, nigba ti won ba ri ise taku taku ti won se, oju yio ti awon naa. Bi won ba si pe won fun iranlowo kia ni won yio se, emi ro wipe eleru lo ye ko koko gbe eru re ni bi to ti wiwo.

Oun to mu mi ko eleyi ni ti pasito Ajidara to sese ku, mi ko ri won RI soju, mi si ba won tan, sugbon o dun mi gidigan nitori ki se igba akoko le yii ti aitete ri iranlowo owo yio pa awon osere ti a feran, mi ni eniyan ninu egbe yii to je osere, emi ki si se osere rara sugbon mo ro wipe imoran yii, yio se won ni anfani ti wo ba le mu lo. Ki Olorun te pasito Ajidara si afefe rere.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment