Smiley face

Itan: SÙÚRÙ GBÈ MÍ (Apá kejì) lati owo Olùkó Èdè Yorùbá Arb

Agogo méwàá ni mo máa ń dé ilé èkó béèni ìyá Adébáyò ti tèé mó mi létí wí pé agogo méjì ò gbodò kojá ìséjú kan bá mi ní kíláàsì tí Màá fi lo mú àwon àbúrò mi ni ilé èkó won.

Ilé èkó gbogbogbòò tí ó jé ti ìjoba ni èmi lo nígbà tí àwon àbúrò mi lo sí ilé-èkó aládàáni.

Òkan nínú àwon Olùkó ilé-èkó wa tí ó ń gbé ní agbegbe kan náà pèlú ìyá-ìyá mi ni ó sàlàyé bí mo se ń pé dé ilé-èkó àti bí mo se máa ń sáré lo mú àwon àbúrò mi pèlú òkanòjòkan àwon ohun tí ó gbó lénu àwon ènìyàn pé ojú mi ń rí.


Ara ìyá àgbà bù máso, wón rántí ìyá mi Àdùnní lójónà.


Ìyá àgbà fi Òrò mi tó àwon ègbón ìyá mi(ìyá mi ni àbígbèyìn ìyá won) létí, wón káàánú mi wón sì fenukò sí wí pé kí ń máa gbé òdò ìyá àgbà láti lè máa sèkejì ìyá àti nítorí ilé-èkó mi nítorí pé yàrá ìkékòó kefà alákòóbèrè ni mo wà, ìdánwò àse wo ilé-èkó Sékóndírì wa sì kù dèdè.


Won ò fi agídí tàbí ipá mú mi kúrò ní ilé wa,àsiko ìsinmi (Holiday) ni ìyá àgbà ní kí ń wá lò tí mi ò fi padà sódò ìyàwó bàbá mi mó.

Báyìí ni mo deni tí ń tètè dé ilé-èkó, mò ń ráyè kàwé mo sì ń jeun lásìkò.


**********************************************
Àsìkò tí bàbá mi wá bèmíwò nígbà tí mo ti wà ní ìpele Olódún Kerin ní Sékóndírì (SSS 1) Nígbà tí bàbá mi wo èsì ìdánwò mi tán tí inú won sì dùn ó lérí fún mi láti tó mi dé ibi tí mo bá fé láti kékòó dé láyé yìí, bákan náà ni bàbá mi rò mí láti dáríjin àwon fún gbogbo ìwà burúkú tí ìyá Adébáyò wù sí mi, àti wí pé kìí se pé inú àwon dùn sí àwon ohun tí ó selè nígbà náà ó kàn jé wí pé inú àwo tí ejò ká sí ni kò jé kí á mo bí a se lè pa á.

Mo wòye wí pé bí mo se ń gbiyanju láti ràn ó lówó ni isé re ń nira síi ni mo se kúkú fi o sílè kí oore mí ó má baà dàbí ti eni tí ń di òkúta sérù re, má bìínú Adébánké mi Àdùké. Ojó yìí gan ni inú mi yó sí bàbá mi.


Òsè kejì tí a parí ìdánwò àsekágbá (SSCE) ni ìyá àgbà so fún mi pé ara àwon ń se bákanbákan, mo bá wolé láti gbé àgbo ìbà fún won, èyìnkùlé tí màá padà sí báyìí ìyá àgbà ti subú láti Orí àpótí tí wón wà, irú kí lèyìí? Mo gbé won móra mo sì ri wí pé wón ti síwó mímí.

Mo ké tòò! Mo logun bíi kóhun mi ó já. Mo gbára dálè bí I kíkú tó mú ìyá ó wá mú mi lo, àmó ikú ò jépè mi. Bí wón se ń mú mi tí wón ń rò mi ni Orí mi túbò ń wú síi😩😩😩😩😩

NJE ÈYIN MO OHUN TÍ Ó SO EKÚN ÀDÙKÉ DI ÀSUN ÀÌDÁKÉ BÍ?

ìtàn yìí ń tèsíwá

Olùkó Èdè Yorùbá Arb (2017)

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment