Smiley face

Itan: SÙÚRÙ GBÈ MÍ lati owo Olùkó Èdè Yorùbá Arb

Bàbá mi nìkan ni mo gbónjú mò gègè bí òbí.

Ohun tí mo gbó ni wí pé odún kejì tí mo dáyé ni ìyá mi térígbaso látàrí àìsàn èyí tí bàbá àti àwon ebí ìyá mi sa ipá lé lórí sùgbón tí kò gbó wíwò.

Léyìn odún keta tí ìyá mi papòdà ni bàbá mi fé ìyàwó mìíràn, tí Gbogbo nnkan sì n dùn fún wa.

Ìyàwó bàbá mi kò mú Osù tí ó wolé wa je, osù kesàn án tí ó wolé wa ni ó bí Omo okùnrin làntilanti.

Inú mi dùn sèsè wí pé èmi náà di alábùúrò, àwon òré mi pàápàá a máa bá mi dápàárá wí pé èmi náà ti di àùntí Àdùké nìyen. (Ó johun pé iyè mi fòó láti dá orúko ara mi télè, Àdùké ni mò ń jé, Àyìndé sì ní órúko bàbá mi)

Adébáyò ni orúko àtèmó àbúrò mi. Nígbà tí Adébáyò lé Osù díè ní Omo odún méjì ni òun náà gba Adéwálé lábùúrò, èyí ni wí pé nígbà tí èmi yóò fi pé odún méjo mo ti ní àbúrò okùnrin méjì Léyìn tí mo sì féràn won dóba.

Yàrá ìkékòó olódún kerin ni mo wà tí isé bàbá mi kò fi lo déédé mó.

Àsìkò yìí ló wá yé mi wí pé owó ní ń fún ni níyì, ìyá Adébáyò tí ó ti máa ń jé bàbá mi ní sa télè wáá di eni tí ń gbó mó bàbá mi bí ajá dìgbòlugi, béè bàbá mi ò tó eni tí ń gbin àbí àse wo ní ń be lénu baálé tí aya ń bó?


Kèrèkèrè ìsípòpadà àṣẹ wolé wa, ìyá Adébáyò doko apàse bàbá mi sì di agbàse nínú ilé, àse ìyá Adébáyò níí múlè nítorí pé bí eni tí ó fi età sàwúre ni ojà rè se ń tà tí ó sì ń gbó bùkátà ilé.

Òdá owó tí ó dá bàbá mi yìí, èmi gan ni ó se lósé nítorí pé ìyá Adébáyò kìí fé rí imí mi láàtàn, ó tilè se ojú ayé fún odún márùn-ún àkókó àmó nígbà tí owó ti wá sáféré lówó bàbá mi, tí àse ìdarí ilé sì ti bó sí owó rè ni ó wá fi bí ó ti jé gan hàn mí.

Èmí nìkan ni mo máa ń se gbogbo isé ilé tí Màá sì tún tójú àwon àbúrò mi ní òpò ìgbà ni bàbá mi máa ń fé láti ràn mí lówó àmó ìyá Adébáyò yóò ri wí pé òun bá mi wásé mìíràn bí bàbá mi bá ti kúnmilówó tàbí rànmílówó.

Nígbà tí ó yá, bàbá mi yònda mi fún ìyá Adébáyò láti máa se mí bí ó bá ti fé nígbà tí àwon náà ti rí enu ilè àti tọkọ́.

NJE ÌGBÉSÈ TÍ Ó DÁRA NI BÀBÁ MI GBÉ NÍPA YÍYÒNDA MI FÚN ÌYÁ ADÉBÁYÒ LÁTI MÁA SE MÍ BÍ Ó TI FÉ?


Ìtàn yìí ń tèsíwájú
© Olùkó Èdè Yorùbá Arb (2017)

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment