Smiley face

Adajo kan agbejoro Evans labuku ni kootu

Ogbeni Olukoya Ogungbeje to je agbejoro fun ogbologbo odaran ti inagije re n je Evan lo ti kan abuku bayii niwaju onidajo Ibrahim Buba ti n joko nile ejo to gaju lo niluu Eko.

Ninu igbejo to waye lojo Eti to koja yii ni Ogbeni Olukoya Ogungbeje ti fesun kan awon onise alaabo nipa wi pe, ona aito ni won gba mu Evans ati wi pe, ifeto-eni-dunni ni bi won se ti Evans mole lati igba yii wa.

Ogbeni Ogungbeje si n so fun ile ejo wi pe, ijoba ni lati sanwo fun Evans gege bi itanran eto re ti won fi dun un.

Leyin gbogbo atotonu, Onidajo Buba da ejo Agbejoro Ogungbeje ati gbogbo isomogbe re nu bi omi isanwo; o ni esun naa ko lese nile rara.

Eleyii to tun wa joniloju ni bi Onidajo Buba se ni ki agbejoro Ogungbeje lo san 500, 000 latari bo se gbe ejo ti ko lese nile wa sile ejo.

Ti e ko ba gbagbe, Evans yii lo ti jewo bi o se gbe awon kan pamo fun osu meje titi di igba ti won ri $1m san. A tile tun gbo wi pe, aimoye emi bo lowo okunrin yii kan naa.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment