Smiley face

Ìtàn Olajumoke arẹwà obìnrin (pt1)

Aaalo o... aaalo... alomi da furugbagbo o da lori omobinrin arewa kan ti oruko re nje Olajumoke.

Olajumoke rewa ju egbin lo, ninu ilu won kò si arewa bii Olajumoke.

Eeyan gbodo fọwọ́ rẹ dára dára ki o tole di imú. Irin ẹsẹ rẹ a maa dani lọrun. Tí i Olajumoke ba n sọ̀rọ̀, gbogbo eniyan a fẹ́ ẹ le máa pọn ẹnu rẹ la.

Kódà awon obinrin ilu won a tun maa jowu ewa rẹ. Ehin ẹnu re funfun bi egbon òwú. Bẹ́ẹ̀ ni àwọ̀ rẹ ń dani lorun nitori ọmọ pupa ni. Irun ori rẹ dudu daradara, ṣùgbọ́n kinni kan ba Ajawo re je... hhmmm... Olajumoke ni ìgbéraga.

Gbogbo okunrin ilu won lo ń dẹnu ìfẹ́ kọọ sugbon ara lo ń fiwon n re, ati olowo ati talaka ati odo titi tofi dori oba ilu gbogbo won ni Jumoke ko jale fun nitori won ko rewa to loju rẹ.

Ni osan ọjọ́ kan okunrin arewa iwin kan wo ilu yìí wa lati bawon na ọjà.

Láàárín ọjà yìí ni o ti se alabapade Olajumoke. Bi Jumoke se ri inu ẹ dun ó ni lónìí olónìí ni maa fi ọkùnrin yìí se ade ori mi....

Itan sese     bere.... e maa bawa kalo

Orísun: Emmanuel Oluwafemi Felix

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment