Smiley face

"Ọkọ mi ń ṣe àgbèrè ni mo fi gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ" - Ìyàwó

O ti tọ bí ọdún mẹ́wàá báyìí tí Sukhwant Kaur àti Azad Singh tí ń fẹ́ ara àwọn báyìí ni Joginder Nagar to wá ní arẹwà orile-ede India.

Ṣùgbọ́n nígbà tó yá Singh bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe àṣemáṣe. Bi i kò má pé wọlé lalẹ. Bákan náà ni wọn rí pẹ̀lú orisirisi obìnrin nígboro.

Àìmọye ìgbà ni ìyàwó má ń bá ọkọ rẹ ja látàrí àlè tí ọkùnrin náà ń yan.

Ṣùgbọ́n lọjọ burúkú yìí, Ọlọ́run nìkan ló mọ ohun tí ọmọbìnrin naa gbọ.

Ò ní sùúrù fún ọkọ rẹ kò sún. Kò tó lagi mọ ọ lórí láti ojú orun.

Lẹ́yìn èyí ló fi ọbẹ̀ ge nnkan ọmọkùnrin re kó tó wá sọ ọ sínú salanga ìgbàlódé. Leyin eyi lọ tún fi omi filọọṣi nnkan ọmọkùnrin ọkọ rẹ dànù.

Inú ìrora ni ọkọ obìnrin náà wá báyìí ni ile ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Àwọn ọlọ́pàá ti gbé obìnrin náà, ìṣe ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni kòmisanna àwọn ọlọ́pàá Jalandhar, Satinder Kumar, tí jẹrí sì wí pé òtítọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment