Smiley face

Áńgẹ́lì kan tí ń jẹ Lára Olubo

Òní, 15/03/18, ní ọjọ́ ìbí ogbontarigi sọrọsọrọ orí afẹ́fẹ́, Lára Olubo.

Arábìnrin Lara jẹ́ akíkanjú ènìyàn eléyìí tí kìí fi ìṣe rẹ ṣeré.

Yàtò sì wí pé ó jẹ́ sọrọsọrọ, ó tun jẹ́ olórin èmi àti onise aṣọ oge to pegede.

Lara Olubo nifẹ Ọlọ́run, ó sì tún nifẹ àwọn ènìyàn gidigidi. Kìí fojú pa ènìyàn rẹ, o si jẹ́ onirẹlẹ ẹ̀dá.

Ọlọ́run fún arábìnrin Lára ni ẹwà tó pọ̀. Eléyìí tó mú ara má fún àwọn ènìyàn wí pé, ó seese kí arábìnrin náà jẹ ọkan ninu awọn áńgẹ́lì tí ìwé mimo sọ wí pé a má rí wọn láàárín àwọn ènìyàn ṣùgbọ́n a kò ní dá wọn mọ.

Ǹjẹ́ bẹẹ wá lo rí?

Ó fẹ́ jọ bẹẹ lójú wa. Lara Olubo kìí bínú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kii sì kúrò lénu rẹ nígbà gbogbo.

Àìmọye àwọn ènìyàn ní wón  ti ń gbé ìgbé ayé tó dùn lónìí nípasẹ̀ Lára Olubo. Tó bá jọ bí asọdun, ẹ gbìyànjú kẹ ẹ wo Ètò Baba Ètò lórí Orísun TV.

Jù gbogbo rẹ lọ, òní ni ọjọ ìbí Lara Olubo, áńgẹ́lì onínú ire.

A fi àsìkò yìí kìi kú ọdún tuntun. A gbàdúrà ire owó , irẹ ọmọ, ire àlàáfíà, ire èmi gigun àti ayọ̀ ìdùnnú . Àmìn

#HappyBirthday

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment