Smiley face

Boko Haram gbiyanju lati fẹ̀mí ṣòfò nínú awẹ Ramadan

Àìmọye èmi ni Boko Haram kò bá rán lọ sọ́run lópin ọsẹ tó kọjá yìí, 20/05/2018, níbi wọn ti n gbìyànjú láti dáná bombu 💣 sì mọsalaasi kan to wá ni Gashua ni ijoba ìbílẹ̀ Gujba ni ìpínlẹ̀ Yobe, eléyìí to padà ja si pàbó.

Gẹ́gẹ́ bí igbakeji alukoro ilé ìṣe ọmọ ológun Nàìjíríà 🇳🇬, Col. Onyema Nwachukwu ṣe ṣàlàyé fún àwọn oniroyin, ó ni àwọn ara ìlú gan-an ni wó  kẹfin obìnrin tó so ìgbànú módìí lábẹ́ aṣọ. Arábìnrin tí ikọọ̀ Boko Haram rán niṣe ikú náà lo ń ṣe bi ẹni fẹ́ jọ́sìn sí ọba Allah nígbà tó wọnú mọsalaasi láì mọ̀ wí pé ẹlẹ́kurú mbẹ lábé aṣọ.

Ìgboyà ni àwọn tó kẹ́fín rẹ fi tú láṣọ wò. Kí wọ́n to fà á le àwọn ọmọ ológun lọ́wọ́.

📸 NAN

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment