Smiley face

Buhari tí de láti UK: Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Orunmila tí ṣẹlẹ̀ sí Buhari

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí padà wálé láti ìlú Biritiko níbi tó ti lọ yọjú sì dókítà tí ń tọju rẹ. Ní alẹ ọjọ́ Jimoh, 11/05/18, ní bàálù aare balẹ sì papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe to wá nílùú Abuja.

Nikete tí aare sọkalẹ nílùú bàálù to gbé dé lo tún bọ sínú bàálù agbẹ́rapá (helicopter) eléyìí to gbé tààrà lọ sínú ilé ijoba Aso Rock.

Nígbà tí Buhari fẹ́ gbéra lọ sí UK ni àwon  ẹgbẹ́ alátakò ń sọ wí pé, "alọ ramirami ni, ati wí pé Baba lè má padà wálé mọ".

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Buhari dàbí ọ̀rọ̀ Orunmila ni lọ́jọ́ tí bàbá ń rode Ọ̀yọ́. Àwọn ọ̀tá ni ti Orunmila bá lọ s'Ọ̀yọ́ kò níde. Orunmila wá ní tọ bá wà sebi tòun ni, "ikọ kìí kejo lọ́nà, ikọ kìí kọ bálá. Àyúnlọ àyúnbọ̀ lọ́wọ́ ń yẹnu. Ẹyẹ kò ní fò kò forí sọ àpáta láéláé". Bí Orunmila ṣe ṣe ni yìí tó sì ségun àwọn ọ̀tá rẹ pátápátá. 😂

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment