Smiley face

Wọn tí dá ọlọ́pàá to mú Evans àti Godogodo lóla nílùú Abuja

Wọn tí fi irawo kún irawo Abba Kyari nílùú Abuja.

Ogbontarigi ọlọ́pàá ọlọtẹlẹmuyẹ to rẹyìn àwọn ògbólógbòó ọ̀daràn bí Godogodo, Evans ajinigbe, China, Vampire àti bẹẹ bẹẹ lọ ní wón kéde igbega rẹ losu diẹ sẹ́yìn láti fi ṣe koriya fún un. Ní báyìí, wọn ti gbé irawo DCP lè Kyari lápá nílùú Abuja. Ìwádìí sì fi hàn wí pé, Kyari ni ọlọ́pàá tí ojọ́ orí rẹ kéré jù lọ ti yoo ni iru irawo bẹẹ.

Kí wá ṣe òun nikan ni wọn gbéga, àwọn isọmọgbe rẹ náà kò lọ lọ́wọ́ òfo. Abba Kyari yìí náà ni wọn gbé ìṣe àwọn adigunjale tí wọn ṣe ijamba l'Ọfa fún, ọwọ́ rẹ sì ti tẹ díẹ̀ nínú àwọn ọdaju ẹ̀dá náà. Kosi tí dáwọ́ dúró.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment