Smiley face

Sàràkí lè dá Buhari lágbo nu

Inúfu-àyàfu ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC wá báyìí pelu ahesọ ọ̀rọ̀ tí ń lọ kiri wí pé, Ààrẹ ilé igbimo asofin àgbà Abuja, Bukola Sàràkí kò ní pẹ fi ẹgbẹ́ onigbalẹ silẹ.

Gbogbo ọna sì ni Ààrẹ Buhari fi ń "gbé-sun-ún-mọ" Sàràkí láti wá ojú ire rẹ báyìí.

Bukola Sàràkí, Waziri ilu Ilọrin Afonja, tí dẹrujẹjẹ nínú òṣèlú ọ̀tẹ̀ yìí àyàfi tí a bá fẹ́ tigbá kan bọkan nínú.

Láti ọjọ́ tí Sàràkí tí gorí aleefa gẹ́gẹ́ bi Ààrẹ ilé igbimo asofin àgbà lo tí n jagun bí kò ṣubú, kàkà kò ṣubú lojú àwọn ọ̀tá, jagunlabi tún gbà irawo kún irawo ni.

Sàràkí wá lára àwọn igi ńlá to padà lẹ́yìn Jónátánì to fi jabọ kíákíá lọ́jọ́si, kò má jẹ wí pé irú ọgbọ́n tí wọn lo nígbà náà ni wọn tún fẹ dá fún Buhari.

Abalajọ tí Buhari fi n pariwo labẹnu wí pé, ikú to pa aladiye kò tún gbọ́dọ̀ tún pa elewure.

Òṣèlú pelu wàhálà! Ẹ jẹ́ ká gbé yẹn tì ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ kan na.

Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọjọ kẹtàdínlọgbon oṣù keje ọdún, 27/07/18?

Osan yóò dòru, òṣùpá ☀ pupa yóò si jáde ní awọ sanmọ. Àwọn onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ so wí pé ìṣẹ̀lẹ yìí kọjá wákàtí kán tí yóò fi ṣẹlẹ̀.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment