Smiley face

Ìdí ti ọga ọlọ́pàá fi pe Sàràkí lẹẹkan síi lórí idigunjale Ọfa - Amofin Olabimtan

Àwọn onwoye nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú tí ṣàlàyé wí pé, kò yẹ kó jẹ ohun ijoloju wí pé oga àgbá àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí tún padà pe Bukola Sàràkí lórí ọ̀rọ̀ ẹsun idigunjale Ọfa, eléyìí tí a kò gbọ ohunkóhun nípa rẹ mọ fún ìgbà pipẹ sẹ́yìn.

Gẹ́gẹ́ bí Agbejoro àgbà Oladapo Olabimtan ṣe ṣàlàyé, ó ní awuyewuye àti rukerudo tí ń ṣẹlẹ̀ lọọlọ yìí ló gunle ọ̀rọ̀ oselu.

"Ohun tó mú oga ọlọ́pàá rántí ọ̀rọ̀ tí wọn ti dásọ bo mọ́lẹ̀ lo niise pẹ̀lú isesi Bukola Sàràkí eléyìí to fi hàn wí pé, ọkàn àti ẹ̀mí rẹ tí kúrò nínú ẹgbẹ́ APC", Olabimtan gbé kalẹ bẹẹ

Nínú ọ̀rọ̀ Amofin yìí ló ti fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé, tí oro Buhari ati Sàràkí bá sì wọ̀, ó seese kí ọ̀rọ̀ náà má rugbo jáde mọ.

Ṣùgbọ́n sá, Amofin yìí ń rọ àwọn ọ̀dọ́ láti ma jẹ irinsẹ òṣèlú lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú. "Àìmọye ọna ni àwọn ọ̀dọ́ fi lè kópa nínú oselu láìṣe wí pé wọn jẹ irinse tí awọn oloselu yóò má lò ní ilokulo láti dá rúgúdù silẹ láwùjọ", Olabimtan mẹ́nu ba bẹẹ.

Amofin yìí tún fi kún un wí pé, gbogbo oloselu bákan náà ni wọn rí. Ìfẹ́ ara àwọn lo ṣe pàtàkì sí wọn ju lọ.

Ó ní àwọn olóṣèlú kii rí àṣìṣe ara wọn ayafi ọjọ́ tí ẹni tí wọn jọ ń ṣe lana bá fi ẹgbẹ́ wọn silẹ bọ́ sínú ẹgbẹ́ míì. Ìgbà náà ni wọn yóò má rí àbùkù ara wọn àti ọna ti wọn gba ṣe aise òtítọ́ sì ara ilu.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment