Smiley face

Asalewa pegedé

Ruth Funke Olapoju (Asalewa)
Mo ronú orin tí mo fẹ kọ, mi ò rí wí
Mo ronú àṣàyàn tí mo fẹ lò, mi ò rí rà.
A ṣe lóòótọ́ tí inú ẹni ba dùn ládùnjù
Àlàyé a má dáni mọ́lẹ̀ bí ọ̀lẹ
Ọ̀rọ̀ a sì fani kù sẹ́yìn bí ẹni tí ò gbédè.
Báwo ni ko ba ṣe dùn tó kí n rewi ọ̀ún ké bí ṣe ń gbemi lọ́kàn sókè. 

Nínú ọgbọ́n orí Asalewa tí jawe olubori. 
Funke lẹ́bùn tó pọ̀ ló fi di gbajúmọ̀ láàárín onísẹ́ ọpọlọ 
ìwọ̀ntunwọ̀nsì lo kàwé lo fi jàre Alákàódì
Amọloju-Amọlẹsẹ, arambara oge bí ọ̀kín 
Ọmọ Olapoju rẹwa lobinrin, ẹ̀gàn ni hẹẹ

Àṣà rẹ kò ní ṣá lójú ayé 
Gbogbo ọjọ́ ayé l'àṣá rẹ ó ma fò lókè 
Ẹwà àṣà rẹ kò sì ní dìkọ̀tì láéláé 
ASALEWA yóò sì ma wá kánrinkáṣe. 



Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment