L'Ojobo to koja yii [25-08-2016], Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi keta ba Aare ile yii, Muhammadu Buhari, lalejo ninu ile ijoba apapo to wa niluu Abuja.
Ipade idakonko ni won se, won ko wi fun oniroyin kankan nipa ohun ti won jo so ni bonkele
Sugbon sa, bi o tile je wi pe awon eniyan n rerin si Aare Buhari ni awon akoko kan seyin, sugbon eto oro-aje to fenu sole pelu airowo na awon eniyan ti je ki won won ma "vexing" bayii si oko Aisha.
Ju gbogbo re lo, Alaafin Lamidi Adeyemi si wa lara awon oba to lenu nibe nile Naijiria. O si seese ko je oro orileede yii naa ni Oosa ilu Oyo lo ba PMB so.
Ju gbogbo re lo, nje eyin mo wi pe ojo keedogun osu kewaa odun 1938 ni won bi Oba Lamidi Adeyemi [15-08-1938]. Ninu osu kewaa odun yii ni baba yoo si se ayeye ojo ibi odun kejidinlogorin [78].
Ojo kejidinlogun osu kokanla odun 1970
ni oko Abibatu gori oye gege bi alaafin ilu Oyo leyin ti oba Gbadegesin Ladigbolu II goke aja lo ba awon babanla re lode orun.
0 comments:
Post a Comment