Leyin aimoye awon aheso iroyin to ti n suyo nipa wi pe Funke Akindele ti se igbeyawo bonkele pelu Abdulrasheed Bello ti opolopo mo si JJC Skillz, agbaoje onisetiata naa ti pada fidi iroyin naa mule bayii.
Bi o tile je wi pe ni awon igba kan seyin, nigba ti iroyin naa jade wi pe Funke ti se igbeyewo bonkele, omobirin naa ko lati je ki awon eniyan mo bo se n lo nipa igbeyawo re.
Awon kan ni igbese re lati se gbogbo eto igbeyawo re tuntun naa ni awo-mosinu-mosikun ko se leyin awon ijakule to ti ba pade saaju lori oro igbeyawo.
Sugbon nibi ipade kan ti ijoba ipinle Eko se agbeteru re to waye niluu London ti won pe ni "Love Lagos Weekend", ibe ni Funke ti fi ara re han nigba to daruko ara re gege bi Arabirin Olufunke Akindele aya Bello". Eleyii si je ka gba wi pe, lotito ni Jenifa ti pada lade lori.
Adura wa ni wi pe, Olorun yoo se igbeyawo naa ni ibujoko ayo fun un.
Ojo kerinlelogun osu kejo odun 1976 ni won bi Olufunke Ayotunde Akindele si agbegbe Ikorodu to wa nipinle Eko. Aipe yii si ni omobirin naa se ayeye ojo ibi ogoji (40) odun laye.
Ki n to dawo duro, e je ki n fi dayinloju wi pe ile Olorun Oba ki i su. Kadara ko si ni tase laelae. Akosile onikaluku ko si ni salai ma se.
Olayemi Oniroyin loruko mi. Ilu Naija ni mo feran ju laye. Ilu awon olopolo ati oniwa tutu bi adaba.
0 comments:
Post a Comment