Smiley face

Asa ati orisiirisii ila kiko ni ilẹ Yoruba

Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọlọpọ ni won gba wi pe asa ila kikọ ti dohun atijọ gẹgẹ bi ero awon eniyan NIBI, sibesibe, tẹni-in-tẹni takisa taatan. A ko le so nipa asa Yoruba lojulowo lai mẹnu ba ila kikọ. 

Bakan naa, orisiirisii itan atenudenu lati gbo nipa orisun ila kikọ. Awon kan gba wi pe ẹru ni won kọkọ kọ nila laye ọjọun fun ijiya ẹsẹ ẹru naa. Sugbon nigba to jina tan lo di wi pe, ila oju re n wu gbogbo eniyan. Sugbon alaye isalẹ yii tun yato diẹ.


Nje kini idi re ti a fi ko ila?
Idahun fun enikeni ti o ba se ibeere yi pin si ona meji. Nigba laelae, ogun ati ote po ni orile –ede Naijiria. 

Lakoko yii ni omo n sonu lairo-tele. Awon alagbara n ko awon omo eni ti ko ni agbara bi ti won ta. Bi n won ti n ko ọmọ won bẹẹ ni n won n ko aya won paapaa. Bẹẹni ọpọ gende ni i sonu, ti a n fi won se awaati lawujo. 

Bi a ti n ko won la n tawon lẹru fun awon orile-ede miiran. Bi awon ti a ta leru wonyi, yala lati idile kan naa tabi ilu kan naa ba pade, won ko ni mo ara won rara. Sugbon awon agbalagba ronu pe o ye ki kini kan bi ami wa, eyi ti n won yoo fi maa mọ ara won. 

Ti won o si le so lẹsẹkan naa nipa ilu ti eniyan kan ti wa ni kete ti aba rii. Ogbon ila kiko yi kii se ti gbogbo orile-ede yii ni lati ibere bikose ohun ti awon eniyan orile-ede yii jogun lati Iwo-Orun nibi ti asa naa ti koko bere.
Alaye keji fun ila kiko ni pe boya awon eniyan Iwo-orun nibi ti asa yii ti bere ro pe yoo bukun ewa ara won nipa sise bee.

Bi a ba wo ju elomira ninu awon Okunrin tabi awon obinrin ti o ko ila, a o ri pe ila naa dara pupo loju opolopo won. Dajudaju, asa lati bu si ewa ara ni iru awon bee ka ila kiko si. “Bi a ko ba tori isu jepo, a o tori epo je isu”. Bi a ba wo finnifinni, a o ri pe ila yi yato si ara won lati agbegbe si agbegbe tabi ilu si ilu nibomiran. 

Awon Oyo nii ko orisirisi Abaja, Pele ati Ture. Nwon tun n ko Abaja meta-meta, tabi Gombo, Keke ati Gombo papo. Awon Ekiti a bu meta-meta ti o gbooro, tabi eyo kan soso ti o gbooro, tabi meta òró lori meta ibu ti o gbooro. Awon Egba ni n ko meta-meta ti ko gun ti ko si gbooro. Awon Ijebu a maa ko meta-meta tabi meta loke, meta ni isale re. 

Awon Owu naa mbu Abaja, nwon si mbu Keke pelu. Pupo ninu awon Ife kii kola, sugbon awon miran nko meta-meta nigba miran. Awon Ijesa nko mefa. Ondo nko meta-meta. Awon Iyagba nko meta-meta ti o fẹ ẹ papo l’eba enu won.

Ogunlọgọ ile la ti pa asa yi rẹ, sugbon opolopo idile wa ti ko fẹ fi asa yii sile rara. Lara awon apẹrẹ iru awon ila ti awon Yoruba ma n ko niwonyi lati fi dawaloju pe awon ila wonyi yato si ara won lati ilu ati ile si ara won.

ABAJA
Eyi ni awon ila meta ti a fa nibu lori ara won tabi mefa ti a to ni meta-meta nibu bakan naa.
ABAJA MERIN
Iyato to wa laarin eleyi ati eyi to ea loke yi ni pe. A bu ila toke ni meta-meta, sugbon a bu eleyi ni merin-merin.
ABAJA ALAGBELE
Iru abaja eleyi ni a ma n bu si oju eniyan ti a si tun gbe meta oro miran le lori.
PELE
Ila meta ti a fa sereke ti o duro looro. O maa nye awon ti o ba bu ila bee. A si maa npe awon eniyan bee ni “peleyeju” fun ewa tii fun won.
TURE
Ila meta kekeeke looro ati meta miran ti o gun ju meta isaaju lo.
KEKE TABI GOMBO
Awon ila ti o gun ti a fa lati ori wa ti o si te woroko logangan aarin oju ati eti si isale eeke.


Gbogbo awon ila oju wonyi lati ekini (1) titi de ekefa (6) lo wopo laarin awon omo Oyo, Ibadan, Ogbomoso, Ede, Iwo ati Osogbo.

Awon ila miiran tun wa ti o fi diedie yato si awon ti o wa loke wonyi.
Opolopo won lo dabi abaja, keke, pele sugbon nwon ko gbooro to abaja, keke ati pele awon Oyo.

Apere awon ila bee niiwonyi:

ABAJA OLOWU
Ila meta oro ati meta ibu ni isale won.


KEKE OLOWU
Eleyi yato si keke ti akoko. Siso ni keke Olowu, bibu ni Keke Oyo.


PELE IFE
Ila meta òró
ILA ONDO
Eyokan soso ti o gun ti o si jinle ni


PELE IJEBU
Ila meta ti o gun die ni


ABAJA EGBA
Meta ooro ati meta ibu, ti a ko lori ara won.


PELE IJESA
Meta looro


ABAJA IJESA
Merin ni ibu.


PELE ATI ABAJA EKITI
Awon wonyi yato si pele ati abaja ti a ti salaye soke nitori pe nwon gbooro pupo ju ti isaju lo.
                                                                   ABAJA EKITI

                                                                        PELE KAN

                                                                      PELE META


Orisun: http://asaatioweileyoruba.blogspot.com.ng/ 
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments:

  1. Asa Ati Orisiirisii Ila Kiko Ni Ilẹ Yoruba - Iroyin Yoruba >>>>> Download Now

    >>>>> Download Full

    Asa Ati Orisiirisii Ila Kiko Ni Ilẹ Yoruba - Iroyin Yoruba >>>>> Download LINK

    >>>>> Download Now

    Asa Ati Orisiirisii Ila Kiko Ni Ilẹ Yoruba - Iroyin Yoruba >>>>> Download Full

    >>>>> Download LINK

    ReplyDelete