Awon Yoruba bo, won ni okun ko le gun-ungun ko ma nibi o ti
gbe sewa wa.
Bi o tile je wi pe orisii awon eniyan kan ti n gbe ni ile Yoruba
fun igba pipe eleyii ti eya ati ede won bara mu, sugbon nnkan bi senturi
metadilogun (17) ni awon eniyan bere si ni se apejuwe won gege bi eya Yoruba,
eleyii ti won wa ni guusu iwo oorun orileede Naijiria.
Ti a ba si n so nipa ohun kan ti o mu awon eyan kan yato,
eleyii to duro bi ami idanimo won, ohun kan yii naa la mo si asa.
Ohun ti a n pe ni asa yii a maa fara han nipa ede enu, iwoso,
eto igbeyawo, isomoloruko, bi a se n kini, bi ase n kole, eto kara kata,
idaraya, orin, ilu abbl.
Sugbon ti a ba n so nipa orin atilu, oriisirisii ona ni awon
Yoruba n lo lati mu inu ara awon dun nigba ti owo ba dile tabi ti ajoyo ba
waye.
Sekere ki i rode ibanuje, nibi sekere ba ti n dun dandan ni
kilu o sole sibe. Bilu ba n ro polapola, awon eniyan a si ma gbe orin. O wa ku
sowo onijo, sebi eni bamowe ni i kan lodo.
Ki a to le gba wi pe orisii orin kan tabi ilu je ara asa awon
eya kan ni pato, awon orin ati ilu naa ni lati je ohun to jeyo tabi lalawu
laaarin eya naa. Idi ni yii ti fi gba
orin ati ilu gege bi okan lara ohun idanimo eya kan gege bi asa isedale won bi
ti omo kaaro-o-ojiire.
Die lara awon orin ibile wa ni
Bolojo
Etiyeri
Ege
Obintun
Apepe
Dadakuada
Rara abbl
Ti a ba n so nipa ilu, awon ojulowo ilu Yoruba ni
Bata
Dundun
Omele
Gudugudu
Gangan
Benben
Sakara
Koso
Abl
Pupo awon olorin aye atijo ti won dide leyin ijeyo awon orin
ibile naa ni won se amulo awon ilu yii ninu awon orin won. Bi o tile je wi pe,
oniruuru orin lo ni awon orisii ilu kan pato to wa ni ibamu pelu agbekale won. Sibesibe,
ko si eyi to ye gere kuro ninu lilo ohun
elo orin to je tile Yooba pombele.
Iru awon orin bee ni
Apala, sakara, were, ajisari, juju, waka, fuji, abbl
Sugbon laye ode oni, pupo ninu awon ilu ajemo asa Yoruba,
tabi awon ti a le pe ni tiwantiwa ni olaju ti n gba kuro lowo wa bi igba orun
gba towo omode.
Pupo ninu awon olorin takasufe, orin pakaleke aye ode oni, lo
je wi pe won ki i se amulo awon ilu Yooba mo bi awon agba olorin atijo bi Ayinla
Omowura, Abibu Oluwa, Lefty Salami, Tunde Nightingale, Haruna Ishola, Yusufu
Olatunji, Batile Alake, Kayode Fasola Ligali Mukaiba, Kasunmu Adio, Sikiru
Ayinde Agbajelola, Dauda Epo Akara, Victor Olaiya, Sunny Ade, Ebenezer Obey abbl.
Gege bi Omowe Seyi Kenny lati eka ti won ti nko eko nipa orin
ni ileewe yunifasiti ilu eko se so, o ni pupo ninu awon olorin aye ode oni loje
wi pe akoonu ati agbekale orin won lo je tilu okeere, kosi si bi won yoo se ko
orin ajoji lai se amulo asa ajoji.
Eyi lo jasi wi pe, ero igbalode ni awon olorin igbalode fi n
po orin po nile agodo orin won, lai se amulo awon ilu tiwantiwa.
Eleyii si n je je ki awon eniyan maa gbagbe awon ohun adidun
ti ojulowo awon ilu wa n mu jade.
Sugbon sa, oloto ni tohun oto, oto ni tolu, oto ni tolu, oto
si ni tolutolu. Onilu ki i fe ko tu, sebi teniiteni takisa n taata. Ina
ajoreyin to n deba asa ati awon ilu isembaye wa lomu ijoba ipinle Ogun, labe
alakoso Senato Ibikunle Amosun, jigiri lati wa woroko fi sada.
Eleyii lo mu se idasile odun ilu ile adulawo lati se igbedide
asa ile wa. Odun ilu to waye losu kerin odun 2017 yii ni i se eleekeji iru
eleyii ti akori re je ‘Igbedide asa wa ninu ilu’.
Kaakiri tibu toro ile adulawo ni awon eniyan ti gbe dide
sokale si Egba alake lati wa sodun ilu ile adulawo eleyii ti won pe ni African
Drums festival.
Bakan naa la tun ri awon eniyan lati awon ilu okeere bi
Amerika, Cuba, Haiti Brazil abbl ti won wa mo adun tin be ninu awo oku ewure ti
n fohun bi eniyan gidi.
Ayeye odun ilu ile
adulawo odun 2017 waye ni gbogan asa ti ipinle Ogun, June 12 Cultural Centre eleyii to kale si
Kuto, ni ilu Abeokuta.
Aimoye
lalade ni won peju pese, Aimoye loyeloye ni won wa nikale. Lara won lati ri
Ooni Ile-Ife odaye, Arole Oduduwa atewonro, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, oba alaso
funfun.
Alaafin Oyo o gbeyin, Oba Lamidi Olayiwola
Atanda Adeyemi III, iku babayeye alase ekeji orisa. Lara awon ori ade ti won
tun sokale nibi odun ilu ile adulawo ni Alake tile egba patapata, Adedotun
Aremu Gbadebo III, Olowu tilu Owu Oba Adegboyega Dosunmu naa o gbeyin.
Baa ti ri ori ade bee lari awon ojogbon,
olorin amuludun ati awon onisetiata, awon gbajumo lawujo ati awon eekan ilu pata
ni won pe sibi odun ilu tile adulawo.
Gomina Ibikunle Amosun kede ibeere odun ilu odun 2017 nipa
lilu ilu to ga niwon ese bata mejidinlogun. Orisii ilu yii kan naa lo si je ilu
to ga ju lo nile adulawo.
Ilu iwon ese bata mejidinlogun sara oto lodun ilu ile adulawo
to waye l’Egbe Alake nitori o tun fi iwon ese bata meji gaju tesin lo.
Bee ni gomina seleri wi pe, todun to n bo yoo tun fi iwo ese
bata meji gaju todunni lo.
Lojo iku erin lakatabu, orisiirisii obe laari. Ojo akoni ode
ba papode lawon ode n fi iremoje dara. Nibi leleke ba ti gbe padejo ni won ti n
pate ojulowo efun gidi.
Nibi ayeye odun ilu ile adulawo, orisiirisii ilu alarambara
lawon omo ayan agalu panteete sori igba, eleyii ti gbogbo agbaye ya wawo bi iran.
Ooni ile Ife, oba Ogunwusi Adeyeye lo salaye pataki ti a ko
fi gbodo je ki asa wa parun. Bakan naa ni Oba Lamidi tu wulewule pataki ilu
nile Yooba ati wi pe, ilu omo kaaro ojire nikan ni ilu ti n soro jade laaarin
gbogbo ilu to wa lagbaye.
Didun Ilu n ro polapola, odun dun, odun si n dun, ilu dundun
dun, inu awon eniyan sin dun rinrin. Ariwo odun ilu ile adulawo sin dun kaakiri
agbaye. Ko wa si ba se fe sodun ilu taa ni bolu, eleyii lo mu Kola Bata sebi
akin. E je ka se bi won ti n se ko le baa ri bo ti ye ko ri gan an.
Odun ilu ki i se fun awon omo Yoruba nikan o, latoke oye to
fi dele yibo pata. Pupo awon orileede ti won wa ni iwo oorun ile afirika bi
benin, togo, Ghana naa peju pese sibe.
Awon orileede ti won wa lati iwo oorun afirika yii ni ati eya
Yoruba ninu won ti won wa sodun ilu niluu Abeokuta. Eleyii si fi ye wa wi pe,
lotito, awon eya Yoruba kan ti won ko leru lo laimoye odun seyin ti gbile ni
awon orileede okeere.
Awon ilu won jo tile yooba, bee lede won fidi re mule wi pe
omo yooba niwon. Ife ni gbogbo won ti fe delu okeere. Ko wa ki n se iwo-oorun
afirika nikan ni ati ri apeere ibi ti asa Yoruba tan de, Cuba ati Brazil naa ko
gbeyin ninu sise amulo awon ohun ti a le pe ni isese Oduduwa baba Yoruba.
Odindin ojo meta lafi lulu legba alake, odindin ojo meta lafi
korin nipinle ogun, odindin ojo meta la
fi jo nile awon omo olumo nibi aso adire ti gbe gbayi, ti lafun funfun tin jowo
jenu si ti gbe n wu ni je.
Eniyan to mo ojulowo orin apala ko le sai mo Ayinla Omowura, Eni
ba mo Egunmogaji dandan ni ko mo Adewole Onilu Ola. Ti Ayinla ba n korin lo
niwaju Adewole Onilu ola a si ma lulu bo leyin. Adewole ti dagba, a mo bi ka mu
kongo ilu dani ko. Onilu ola pidan lodun ilu, lala lu gongon so.
Opo awon
ololufe orin apala ni won jade wa forin gbe ilu Adewole laruge.
Nibi a ti n lulu naa lati n korin, Abideen Yusuful Olatunji,
omoomo ologbe Yusuf Olatunju, naa fi sakara dara. A se lotito loro awon agba,
won tina ba ku afeeru boju, bogede ba ku a si fomo re ropo. Abideen Yusuful
Olatunji naa se gudugudu meje , yaya mefa lodun ilu ile adulawo.
Lara awon eekan ti won peju sibi odun ilu ile adulawo ni
minisita fun eti gbo ati asa, Alaaji lai Muhammed. Baba yii se alaye igbelaruge
asa wa gege bi ohun kan to tun le pawo wole fun orileede naijiria. Oro Alaaji
Lai Muhammed ko yato si tawon ologbon onilaakaye ti won ti soro saaju. Sebi oro
awon ologbon a maa jora won, tawon omugo ni yegere.
Odun ilu dun o, se ijo le fe ni abi orin, koda awon onidan
padan awo-dami-enu.
Opolopo awon eniyan ni won gbe oriyin fun ijoiba ipinle Ogun
fun agbekale odun ilu ati akitiyan won lati ma je ki asa wa parun.
Lakotan, ki n to maa lo, e ma gbagbe wi pe ajeji owo kan
Ko gberu doru. Bi asa wa ko ba ni parun, o dowo gbogbo o.
Tidi ba baje, tonidi ni ida. Nitori ohun teni teni takisa n taatan.
0 comments:
Post a Comment