Smiley face

Ejika Ife

O ti pe die ti mo ti ri Omolara. Igba ti mo ri kehin naa ni igba ti mo fi sile ni ile iwe. Sebi oro ile iwe dabi odo to n san ni, awon kan se n lo ni awon kan n de.

Yato si wi pe gbongan ibugbe wa je okan naa, eka ikekoo ede kan naa ni emi ati Lara wa pelu.

Sugbon lale ana ni mo gbiyanju lati wo aworan Omolara lori ero whatsapp. Omolara ti dagunbaniro alaso funfun to duro wamuwamu, pelu ehin funfun to fe keke to un ti igo dudu oju re to fe bi ewe koko.( Igo dudu fenfe lasa tuntun to tun gbode)

Sugbon akole ori ero whatsapp re yii dohun ti mo gbesun bi asaro okan.

"Love when spelt backward phonetically means evil"

'Kiko "ife" lati eyin wa ni ilana adako fonetiiki tunmo si "ibi"'


Adanwo ni fe, ere gele nife je, oja okunkun loro ife jo loju mi.

Awon ti won ba ri ire nibe ni mo ki ku adun ife. Ka maa puro, ohun to fe e dun bi ife otito o si laye. Imo tara eni nikan lo sori ife kodo.

Olayemi Oniroyin, aimoye eniyan ni ko si mo lonii nitori oro ife yii naa ni. Nigba ti elomiira o je ara aye bee naa ni won o si je ero orun.

Ohun ti Adaniwaye ba fi ran onikaluku ni ko maa je bi ise. Sugbon maa ranti ko to fina jo eni fi okan tan o tan, to ba se iwo ni won fina jo bawo ni o se ri lokan re? Gbogbo igba ti o ba ti n wu iwa odale maa seranti oba oke to mo opin ohun gbogbo.

28EEEAE2
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment