Edumare lo n gbe eda ga laye, ogbon eda ko ni itunmo si ohun ti oba oke yoo se.
Gbajugbaja onkorin agbaye, Aliaune Damala Badara Akon Thiam ti gbogbo eniyan mo si AKON ti so wi pe igbe aye oun, iyanu lo je fun oun alara gan-an.
Akon so wi pe Senegal ni won bi oun si gege bi won se bi opolopo omo adulawo sinu igbe aye alaini ireti bi ojo ola o se ri.
Akon ti a bi ni ojo kerindinlogun, osu karun-un odun 1973 (April 16, 1973) so wi pe ona ara ni ohun gba de ilu Amerika nibi ti ohun ti lo opolopo igbe aye ohun. O ni oun si dupe nibi ti Olorun gbe oun de lonii yii.
Aimoye olorin agbaye ni Akon ti ba sise po, lara won ni Eminem, Michael Jackson, Lady Gaga naa wa nibe,Snoop Dogg,David Guetta wa lara awon olorin ti Akon ti ba sise opolo, Lil Wayne,Young Jeezy, T-Pain, DJ Khaled wa ninu akosile wi pe Akon ti ba won fi ise orin dara lorisiirisii.
Awon aseyori Akon salaye ipo re laaarin awon olorin agbaye gege bi onkorin pataki. Igba marun-un otooto ni oruko Akon jeyo ninu amin eye agbaye Grammy gege bi olukopa.
Akon gege bi musulumi ododo so wi pe oun ko fenu kan siga tabi otin ri laye oun, eyi si je iyanu nla eleyii ti o nira fun opolopo awon eniyan lati gbagbo gege bi ise to n se.
"Iyanu ni igbe aye mi! Ipokipo ti eda ba de laye ogbon ori re ko rara. Olorun oba nikan ni i gbe eniyan ga laye. Mo dupe ipo mi lonii. Mo si gba wi pe ola mi yoo tun daa ju ana lo" -Akon.
28EEEAE2
Sent from my BlackBerry wireless device from MTN
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment