Aibale okan ti de ba Aare Naijeria, Goodluck Jonathan pelu awon oro to n rugbo bo to so wi pe awon omo ile igbimo asofin agba kan ti won je omo egbe PDP tun ti fe wole sinu egbe Bola Hamed Tinubu ti a mo si APC.
Aare Jonathan ti ran David Mark to je olori ile si won lati be won wi pe ki won gbe suuru je. Aimoye ipada ni David Mark ti se pelu won sugbon ko si okankan ninu awon ipade naa to yori sibi to suwon rara.
Lowolowo bayii, awon omo egbe PDP ti won wa ni ile igbimo asofin agba je metalelaadorin (73), APC je metalelogbon(33) Labour Party ni ayo ti won pe meta (3) nigba ti omo egbe All Progressives Grand Alliance ko ju eyo kan pere lo(1).
Bakan naa awon omo ile igbimo asoju-sofin ti won kuro ninu egbe PDP bo sinu egbe APC ti salaye wi pe odo awon kii san ko boju weyin lailai.
Gege bi asofin Zakari Mohammed lati Ipinle Kwara se so, oni ko si ohun ti PDP le se lati fa awon pada seyin. O ni ihale lasan ni gbogbo gbigbo ti awon igbimo egbe PDP n gbo lati ye aga mo awon nidi lati igba ti awon ti fi PDP si le fun won.
Lori ti awon omo ile igbimo asofin agba ti eye ti won naa n mura ati fo lo ba APC, odun to n bo ni gbogbo ohun to pamo yoo foju han sode.
Se ipadabo Aare Goodluck fun odun 2015 yoo rorun bayii?
Home / Yoruba
/ "Dafiidi...Dafiidi...Dafiidi!!! E e Melo Ni Mo Pe o? Omi Ko Mo Gbodo Tan Leyin Eja Mi" Aare Goodluck Jonathan Ti Ke Gbajari
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment