Olori awon omo Boko Haram, Abubakar Shekau ti fi fidio tuntun ranse si ijoba ile Naijeria nibi to ti n leri ati fi opolopo emi sofo lodun 2014.
Gege bi oro re, oni ife Allah ni lati se awon nnkan ti oun se. O si salaye wi pe kesekese leri, kasakasa tun un bo leyin to je baba kesekese.
Abubakar Shekau ti awon kan ro wi pe o ti ku lo tun so nipa $7 million eleyii ti ijoba Amerika gbekale ati $312,500 ti ijoba Naijeria ko sile fun eni to ba le juwe ibi ti okunrin amokunseka naa wa.
Abubakar fi oro ranse si ilu Amerika, o ni won o leye mu iye lasan ni won yoo ma wo leyin eye.
Ninu fidio yii naa ni okunrin yii ti menuba wi pe oun ni irumale to yabo baraaki awon omo ologun Naijeria to wa ni Bama ni Ipinle Borno ni ogunjo osu kejila odun yii nibi ti oun ti fi emi soja sofo ti oun si ko aya ati awon omo won leru.
"Odun 2014 maa bu ata soju nitori wi pe Allah mbe leyin mi. Bi mo se n ge ori ni i ma ge won lese, ti n si maa se won ni sibala-sibolo." Abubakar Shekau
Home / Yoruba
/ "Odun 2014 Ma Bu Ata Soju Gidi Gan." Abubakar Shekau To Je Olori Awon Boko Haram Ti Salaye Sinu Fidio Tuntun
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment