Smiley face

Odun Irawo Meji: Femi Adebayo ati Odunlade Adekola



Irawo meji se ojo ibi lonii, boya leyin mo?

Odunlade Adekola ni irawo kinni nigba ti Femi omo Adebayo si je eleekeji.

Ojo kokanlelogbon osu kejila odun 1977 ni won bi Odunlade Adekola. Omo ilu Ekiti ni sugbon itan so fun wa wi pe Egba Alake lo dagba si ibe naa lo si ti lo ile iwe alakobere ati girama ko to di wi pe o darapo mo ise sinima ni sise.

Ojo kokanlelogbon osu kejila naa ni won bi omo Oga Bello ti n je Femi Adebayo ni odun 1972. Omo Ilorin Afonja ni sugbon ilu Eko ti Raji Fasola ni won bi si. O si keko gboye nipa imo ofin ni Ifafiti ti ilu Ilorin ko to gba ile eko awon amofin lo nibi to ti lo keko ti ori re si pe perepere bi alajo Shomolu.
Ati igba yii naa ni Femi ti darapo mo egbe tiata baba re ti won pe ni Awada Keri-Keri School of Performing Arts.

Leyin eyi tun ni Femi tun lo gboye eleekeji (Masters in Law) ninu imo ofin ni ile iwe Ifafiti ti ilu Ibadan.


Femi tun je omo egbe akekoo Institute of Chattered Secretaries and Administrators of Nigeria. Bakan naa lo tun je omo egbe Junior Chamber International.

Odun 2005 ni a le so wi pe Odunlade Adekola so ise tiata dowo nigba to je wi pe Femi Adebayo gbonjuba ise tiata lowo baba re ni.

Awon mejeeji ni won ni ile ise tiata ti n pa owo gidi. Odunlade Adekola Productions ni ti broda giga nigba ti J-15 Media Network je ti broda Jelili.

Lonii ni Femi Adebayo pe omo odun mokanlelogoji (41years old) nigba ti Odunlade Adekola pe eni odun merindinlogoji (36 years old).

A ki won ku odun, a si tun ki won ku ori ire.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment