Ati igba ti Gomina Aliyu Wamakko ti ilu Sokoto ti pinnu lati fi egbe PDP sile bo sinu egbe APC, ti igbakeji re si yari wi pe wi egbe alaburada to gba oun nigba ojo ni oun yoo tele nigba erun ni wahala ti bere ni ipinle naa.
Ti surutu si n fi joojumo pariwo kiri igboro ti n wi pe ' Ijangbon yah zo, wahala yah zo'.
Ija nla be sile ni aaro ana ni agbegbe Dendima ni ilu Sokoto nibi ti PDP ti wo sokoto kan naa pelu APC. Aimoye awon eniyan ni won na sare bi eni wi pe ki won ma mori dele, aimoye farapa bi eni wi pe ogun jalu ni, aimoye dukiya lo si sofo bi eni wi pe ko si oluso.
Awon egbe mejeeji ti dana sun ofiisi ara won bayii. Ija naa buru to bee gee to je wi pe awon olopa alaso dudu ko ri oro naa yanju a fi igba ti awon godogodo omo ologun de ki efiribodi to tuka ti won si sare lai duro mu sokoto ti n jabo nidi won.
E maa gbagbe wi pe ana ode yii kan naa ni won fun Senato kan nibon ni Ipinle Rivers nibi egbe APC ti pe jo eleyii ti won fi esun re kan Aare Jonathan.
0 comments:
Post a Comment