Sebi ile oba to jo ewa lo bu si, ile ise oko akero ofurufu Dana Air ti ra baalu tuntun Boeing 737-500 series aircraft mo awon baalu ti won ni tele.
Ana ode yii ni won ja ora lara baalu naa nigba to bale si papako ofurufu Murtala Mohammed to wa ni ilu Eko.
Awon osise ijoba ti won n dari eka oko irinna ofurufu, Nigeria Civil Aviation Authority ti ye baalu naa wo. Abajade ayewo won si ni wi pe alaafia ara baalu naa da sakasaka.
Ti e ko ba gbagbe, osu to koja yii ni ijoba sese da iwe ase irinna ile ise naa fun pada lati pada si enu ise re lakotun.
O ya, e je ka fo loke pelu oko ofurufu Dana Air to gbamuse.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment