Smiley face

Musa Yar'Adua: Agbara, Ipo ati Iku

Ojo kerindinlogun osu kejo, odun 1951 (16 August 1951) ni won bi ni Ipinle Katsina. Ojo Karun-un osu Karun-un (5 May 2010) lo dagbere fun aye yii ni eni odun mejidinlogota (58yrs) ni ilu Abuja.


Alh Umaru Musa Yar'Adua ti je gomina Ipinle Kastina laaarin odun 1999 si odun 2007 (29 May 1999 – 29 May 2007) ko to wa je Aare lodun 2007 si 2010 (29 May 2007 – 5 May 2010).


Odun 1975 lo fe Turai Yar'Adua, bakan naa lo tun so yigi fun Hauwa Umar Radda lodun 1992.

Omo mesan-an (9) ni Alh Umaru Musa Yar'Adua bi, Ifafiti Ahmadu Bello lo si ti kawe jade.


Lara awon oro aheso ti a gbo ni wi pe kii se ife okan Yar'Adua ni lati di Aare latari ipo ailera to wa. [Awon kan so wi pe Obasanjo lo fi tipatipa gbe dide gege bi oludije fun ipo Aare eleyii ti ko si aridaju fun wa].

Bakan naa la tun gbo wi pe Musa gba wi pe rikishi po ninu ibo to gbe oun wole gege bi Aare saaju ojo iku re eleyii to ko lati tanna imole si latari iha ti egbe re le ko si iru igbese bee.


Eniyan jeje ni Musa a si tun gbo wi pe olusin Olorun gidi ni.

Musa Yar'Adua ti ku, sugbon ohun ti akosile so nipa re si ku.

Ki Oluwa bukun Orileede Naijeria!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment