Ijoba apapo lagbo wi pe won ti gboju kuro ninu obitibiti owo tabua to le ni irinwo bilionu owo naira (N446.3bn) eleyii ti Muhammed Abacha ati baba re, Sani Abacha jigbe ninu apo owo ijoba.
Isele yii ni ajo kan ti kii se ti ijoba ti n gbogun ti iwa ibaje, Transparency International ti koro oju si bayii. Won ni igbese Aare Goodluck dabi eni wi pe o n se agbateru fun iwa ibaje lawujo.
"Allowing the theft of public funds to go unpunished sends the wrong message that those with powerful connections can act with impunity.
The case should have been fully prosecuted and the government has not given adequate reasons for dropping the charges.'' Ajo T.I lo so bee.
Sugbon gege bi akowe fun minisita fun eto idajo, Ambrose Momoh se so.
O ni; ' eyin eniyan mi, se e o jasi bo se n lo ni? Ori ijoba ko daru ke. Ijoba si mo idi pataki to fi ni ki ile ejo gboju kuro ninu ejo Muhammed Abacha.
Se eyin o mo wi pe owo ti Sani Abacha ni lawon ilu okeere po bajebaje to je wi pe oko tirela ogorun ko le ko won tan. Muhammed Abacha si ti se ileri lati ran ijoba lowo nipa infomesan awon ilu ti owo naa wa ati bi yoo se pada si owo ijoba apapo
Se e ri ejo irinwo bilionu to wa ni kootu, owo guguru atepa lasan ni ko ni meaning.'

0 comments:
Post a Comment