Smiley face

Won Ti Gbe Fayose Lo Si Ile Ejo

Leyinoreyin, egbe APC ti Ipinle Ekiti ti pada gbe ejo kotemilorun lo siwaju igbimo oludajo ti won risi awuyewuye eto idibo nipa eto idibo to gbe Fayose wole gege bi gomina ti gbogbo ilu dibo yan ni Ipinle Ekiti.

Alaga egbe APC, Oloye Jide Awe lo kowe ipejo naa ni ilu Ado Ekiti. Lara esun won naa ni wi pe egbe PDP lo ona alumonkoroyi nipa lilo opolopo soja lati doju ibo ru.

Ohun ti o ya ni lenu ju ni wi pe ipejo yii waye leyin ti Gomina Fayemi ti gba wi pe oun fidiremi ninu eto idibo to waye to si ki Ayodele Fayose ku ori ire Ayo re to pada dele layo.

E gbo ohun ti alaga egbe APC fun Ipinle Ekiti wi lori oro naa:

"The governor does not own the party. It is the party that owns the governor, and so the party can decide for him.

You will observe that there is no name of Dr Kayode Fayemi on the ballot papers, what was on it was the name of the party and its logo.

So, the issue is beyond the governor. Let it be known to you that our candidate, Dr Fayemi only conceded victory to guarantee continued peace that was prevalent in the state at the time as well as allow the siege laid on the state by the military to end.

You can see that as soon as he announced that he had accepted defeat, the soldiers immediately vacated the state."

Lara awijare Oloye Jide Awe to je siamaanu egbe APC Ipinle Ekiti ni wi pe Ayodele Fayose ni opolopo ebo leru eleyii ti ko ye ko tile dije tabi gbe apoti idibo debi wi pe yoo maa yan fanda gege bi Gomina.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment