Kcee, okan ninu awon olorin igbalode ilu Nigeria fi emi imoore re han si Olorun nigba ti awon oniroyin amuludun ba lalejo.
Okunrin yii mu won kaakiri inu ile re lati fi die han won nipa dukia to ni, eleyii to se apere won gege bi ibukun ti oba adaniwaye fi se e loore nidi ise orin kiko.
Okunrin naa tun so wi pe iyanu ni igbe aye oun je ti a ba n so nipa orin kiko nitori awon kan sebi oun ko ni yo jade rara laarin awon olorin Naija sugbon oba oke ju eniyan lo.
Kcee se alaye wi pe aimoye itan igbe aye oun ni oun si maa royin sugbon asiko ko ti to nitori itan to gun ni.
0 comments:
Post a Comment