Smiley face

Odun Tomato dun yungbayungba niluu Spain

Odun Tomato niluu Spain
Gẹgẹ bi itan isẹdalẹ Yoruba se fi ye wa, ẹni ti won kọkọ kọla fun, ika ni won fi se fun-un. Igba to ya ni ila kikọ doge nilẹ Adulawọ. Bẹẹ gẹgẹ lọmọ se sori pelu odun tomato ti won pe ni La Tomatina  to maa n waye orileede Spain. Odun 1945 ni itan so wi pe odun yii bere. O si bere nipa rogbodiyan to waye lagbo ariya kan niluu Valencia to wa ni orileede Spain. Nigba ti awon eniyan ko mo ohun ti won yoo ma so mọ ara won mọ, ni wọn ya wọ isọ awon onitomato to wa lagbegbe naa ti won si bẹrẹ si ni so tomato lu ara won bi ba eniyan ju ogulutu.

Awon ololufe n gbadun ara won lodun Tomato
Sugbon bayii, o ti wa di asa, eleyii ti aimoye awon eniyan n ya wo ilu Spain lọdọọdun lati lọ wo ara orisiirisii to maa n waye ni La Tomatina. Ilu Valencia to wa ni Buñol ni odun yii ti maa waye ni orileede Spain. Ojoru (Wesde) to ba si keyin osu kẹjọ (August) ni odun naa ma n waye.

 







Awon ololufe n jo "kerewa" lodun tomato
 





Odun onitomato dun, eyin naa le gbera wo ilu Spain losu kejo odun lati lo jegbadun La Tomatina to maa n waye ni Valencia.

E ku ikale!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment