Smiley face

Awon eniyan korò oju si Ooni Ogunwusi

Obafemi Martins
Ọpọlọpọ awon eniyan ti bẹrẹ si ni juko abuku si Oba  Adeyeye  Enitan Ogunwusi, Ooni ile Ife, bayii pẹlu bo se se abẹwo si ogbontarigi agbaboolu Naijiria, Obafemi Martins.


Sebi won ni inu ẹni ki i dun ka pa mọra, Obagoal lo ju foto Ooni sori ayelujara ni akoko ti oba to kawe gboye ninu im isiro owó se abẹwo si i.

 O jọ bi ẹni wi pe abewo Arole Oduduwa sile agbabọọlu ti n gba bọọlu jẹun niluu China ko fi taratara tẹ awon kan lọrun pelu awon iriwisi to jade leyin ti foto naa ti doju iworan.

Awon kan ni awon abẹwo Ooni to ti n se saaju mu itumo gidi dani, nitori wi pe, awon abewo naa fi ifẹ mulẹ laaarin awon saaju ile Yoruba ni. Ninu ero won, won ni ki i wa sebi ki ọba ma fo jade fokifoki kaakiri ma ki taja-teran nile. Won ni iru awon abewo yii dabi igba ti oba alaye naa n fi ori ade wọle lasan ni.
Sugbon sa, ohun to koju sẹnikan eyin lo kọ si awon mii. Awon kan ni a ko le da Ooni asiko yii lebi nitori wi pe, enikeni ko mo ajọsepọ to wa laarin Ooni Ojaja II pelu Obafemi saaju ko to jọba. Sebi awon Yoruba naa lo wi pe, atanamana ko to atonimoni.

Awon kan tun ri gege bi emi irẹlẹ eleyii ti won lo n fi Ooni Adeyeye han gege bi asaaju rere nile Yoruba.
Akoko ti Obafemi se abewo si Oba n'Ile Ife
E ma gbagbe wi pe, Obafemi naa ti se abewo si Ooni nikete to gori ite niluu Ile Ife.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment