Smiley face

Asiri ohun ti Cristiano Ronaldo n se to fi derujẹjẹ ni yii

Gege bi alaye awon onwoye, ati doke ko nira bi ati duro soke nigba gbogbo. 

Aimoye awon eniyan ni won simi sara latari okiki ati iyi ojiji ti won ba pade nidi ise won. Sugbon akoba nla to lewu ni, nigba ti ẹda ba ro wi pe oun ti de opin irin ajo. 

Lati je eni iyi ati ẹyẹ, joojumo ni ilakaka wa gbọdọ ma tesiwaju, ki aseyori wa tun le gọbọi.
Cristiano Ronaldo ni yii, pẹlu gbogbo ọla ati iyi rẹ, sibesibe, gbogbo igba ni ki i simi lati jẹ eni iyi nigba gbogbo.

Bakan naa lo si n ro ona ọtun lati jọ aye loju. Njẹ eyin naa ronu bi C. Ronaldo?
Olorun lo ni aseyori, ti ẹ ba doke, ẹ ma simi sara. E ma je ki aseyori yin ko si yin lori.
E wa ọgbọn kun ọgbọn, ẹ wa imọ kun imọ. Ẹ tayọ oye ẹda, ẹ derujẹjẹ nidi ise yin. E gbe ile aye ti itan o ma sọ nipa yin laimoye odun tẹẹ ba ti lọ.
 Mo gbadura wi pe Edumare yoo gbe yin ga nidi ise yin. Amin




Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment