Smiley face

Ènìyàn mé̩rin pàdánù è̩mí lé̩yìn tí wó̩n mu Ògógóró ní il̀lú Abeokuta

- Kehind Oladeji 


Kò dín ní ènìyàn mé̩rin tí wó̩n ti pàdánù è̩mí wo̩n léyìn tí wó̩n mu o̩tí ògógóró ní ìlú Abeokuta.

Ariwo ńlá ta ní Ibara Housing Estate, Abeokuta nígbà tí àwo̩n géńdé mé̩rin di olóògbé látara wí pé wó̩n mú àmujò̩ o̩tí ìbílè̩ tí a mò̩ sí ògógóró.

O̩rúko̩ àwo̩n tí ó jáláìsí náà ní Baba Onwenue, Baba Imeko àti Easy sugbo a kò tíì mo̩ orúko̩ e̩nì ke̩rin.

Ìròyìn tí a gbó̩ so̩ wí pé o̩wó̩ àwo̩n o̩ló̩pàá ti te̩ ò̩gbé̩ni as̩ó̩géètì kan tí orúko̩ rè̩ ń jé̩ Taloju, e̩ni tí a gbó̩ wí pé ó ń ta o̩tí as̩ekúpani náà ní iwájú só̩ò̩bù kékeré kan tí ó yo̩ sí iwájú ilé ńlá tí ó ń s̩ó ní agbègbè náà.

O̩kùnrin náà ní ó ti lé ni ogún o̩dún tí ò́un tí ń ta o̩tí ní agbègbè ò̩hún, tí irú èyi ò sì s̩e̩lè̩ rí, àti wipé òun pàápàá mu nínú o̩tí náà ló̩jó̩ tí ìs̩è̩lè̩ aburú yìí wáyé.

Mé̩ta nínú àwo̩n o̩kùnrin náà kú ní o̩jó̩ ajé tí ìs̩è̩lè̩ náà wáyé nígbà tí e̩nì ke̩rin sì kú ní o̩jó̩ kejì ní ilé ìwòs̀an.

Ó gba àwo̩n agbófinró ní is̩é̩jú mé̩è̩dógún kí wó̩n tó rí Taloju gbé lo̩ sí àgó̩ wó̩n nítorí ó̩ ti yó nígbà tí wó̩n ma fi dé ò̩dò̩ rè̩ kò sì s̩ètan àti jò̩wó̩ ara rè̩ sílè̩ fún wo̩n.

Ògbé̩ni Abimbola Oyeyemi, alukoro àgó̩ o̩lo̩pàá Ibara, ti s̩àpèjúwe ò̩rò̩ náà bí àheso̩ àti àhegbó̩.

Nínú ò̩rò̩ rè̩, ó ní "A ò tíì rí kí e̩bí àwo̩n tó kú náà ó wá fí e̩jó̩ sùn. A ò sì tíì fí ojú rí òkú ìkankan nínú àwo̩n tí ó saláìsí náà. Bí ó tilè̩ jé̩ pé a ti mú e̩ni afurasí náà, a ò lè gbáralé o̩rò̩ e̩nu rè̩ nítorí ó ti yó kátankàtan sì ni ó pò̩ jù nínú ohun tí ó ń so̩".








Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment