Smiley face

O TI DI OFIN; ENIKENI O GBODO TA OJA LOJU POPO MO - AMBODE

- Kehinde Oladeji 
Ni ohun ti a le ka si aba lasan tele ni ijoba ipinle Eko ti so di ofin bayii pe ki enikeni o gbodo ra tabi ta oja ni popona Eko mo.


Ni osu ti o koja ni gomina ipinle Eko, Akinwunmi Ambode, so wipe oun o fe ki enikeni o pate tabi kiri oja na awon ojuna Eko mo tori awon ewu ti awon oloja bayii ma n doju ko.

Abadofin yii ni o waye leyin ti oko BRT pa omokunrin kan ti o n kiri oja loju titi nigba ti o n gbiyanju ati sa fun awon osise ijoba ti won gbogun itaja nibi aito ati imototo agbegbe, KAI.

O kere tan, ojo BRT  mejila  ni o ba isele naa lo lojo naa ni bi awon odo agbegbe ti dana sun won loju titi.

Gomina Ambode ti ke so bayii wipe ki gbogbo awon oloja o lo fidi mole tabi ki won wa ibi ti won ti ma sowo won yato si oju popona. Ewe, kii wa se awon ontaja nìkan ni oro naa kan o, enikeni ti o ba ra oja lowo awon eniyan yi pelu yoo foju wina ijoba.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment