Smiley face

Dimeji Bankole ti lo fori bale niwaju Oodua n'Ile Ife

Bi o tile je wi pe opolopo ni ko gbo nipa olori ile igbimo asoju-asofin nigba kan ri, Dimeji Bankole, mo, sibesibe ipo ati agbara re lagbo oselu si wa sibe bi oke olumo ti mbe l'Egba Alake.
Gege bi iwadii pataki ti Olayemi Oniroyin se nipa eni ti ojo ori re kere ju lo ti yoo je adari ile igbimo asoju-asofin Naijiria ninu itan, ohun ti a gbo ni wi pe Dimeji Bankole naa n mura lati du ipo gomina ipinle Ogun labe asia egbe PDP leyin ti Amosun ba pari isejoba re
Awon eleti-ofe Olayemi Oniroyin niluu Abeoukta si fi ye wa wi pe, awon agba to lenu loro si ni okunrin naa ti bere si ni se abewo si ni bonkele

Bakan naa, Dimeji Bankole ti se abewo e-n-le-nibeun si Ooni Adeyeye Ogunwusi ninu aafin re. Oun ati awon emewa re ni won jo kowo rin wolu Ile Ife pelu aso funfun, igba ti won si dewaju Arole Oodua ni gbogbo won na felefele ti igaaya won si kanle dedeede.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment